Home ÀKỌ̀TUN iṣẹ́ yanturu n bọ̀ lọ́nà f’áwọn ọmọ Nàìjríà – Osinbajo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 5, 2021

iṣẹ́ yanturu n bọ̀ lọ́nà f’áwọn ọmọ Nàìjríà – Osinbajo

iṣẹ́ yanturu n bọ̀ lọ́nà f’áwọn ọmọ Nàìjríà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Wọ́n ní ọwọ́ tó dilẹ̀ lèṣù ú lò.
Ilee ṣẹ to n ri si imọ ẹrọ, Microsoft ati ijọba papọ ti buwọlu adehun kan lati da iṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun silẹ fun awọn ọmọ Naijiria laarin ọdun mẹta si akoko yii.

Lara eto naa ni lati ṣagbekalẹ awọn irinṣẹ ti yoo mu ki ikanni ori ayelujara ja fafa sii ni Najiiria.

Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo lo fi ọrọ naa lede lasiko to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ loju opo Twitter rẹ.

Microsoft sọ ninu atẹjade kan pe awọn ti ni ifọrọwerọ pẹlu ijọba Naijiria lati jawe sobi bi eto imọ ẹrọ ni Naijiria.
Aarẹ ileeṣẹ naa, Brad Smith ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun nnkan bii miliọnu marun un eeyan lati asiko yii si ọdun marun un.

Lati le jẹ ki igbesẹ naa rọrun, Microsft ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun olukọ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ti yoo ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọmọ Naijiria atawọn oṣiṣẹ ijọba labẹ eto naa.

Aarẹ ileeṣẹ naa, Brad Smith ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun nnkan bii miliọnu marun un eeyan lati asiko yii si ọdun marun un.

Lati le jẹ ki igbesẹ naa rọrun, Microsoft ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun olukọ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ti yoo ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọmọ Naijiria atawọn oṣiṣẹ ijọba labẹ eto naa.

Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ni ibaṣepọ tuntun yii jẹ ọkan lara awọn ijiroro ti oun ti kọkọ ni pẹlu Aarẹ ileeṣẹ naa loṣu kinni ọdun yii, iyẹn Brad Smith.

Pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn han lori ikede ọhun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…