Home ÀKỌ̀TUN Ilé aṣòfin àgbà l’Abuja sọ pé kò sí ẹ̀rí tó dájú láti yọ Pantami
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 3, 2021

Ilé aṣòfin àgbà l’Abuja sọ pé kò sí ẹ̀rí tó dájú láti yọ Pantami

Ilé aṣòfin àgbà l’Abuja sọ pé kò sí ẹ̀rí tó dájú láti yọ Pantami

Ọrẹ Òtítọ́jù

Èèyàn tó bá ti ní baba nígbẹ̀ẹ̀jọ ,bó bá rojọ́ ẹ̀bi àre ̣ ni.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti n ké pe ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari láti fún Pantami ní ìwé e gbélé è rẹ lórí ẹ̀sùn pè ó ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí.

Kódà, fọ́nrán ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Pantami sọ láti ṣe àtìlẹ́yìn fáwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ti lu orí ayélujára pa.

Awọn kan tiẹ tun da ile aṣofin agba niluu Abuja lẹbi pe wọn ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ nigba ti wọn ṣe ayẹwo awọn orukọ awọn eeyan ti Buhari fi ranṣẹ sile fun ipo minisita.

Ṣugbọn nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, alaga igbimọ eto iroyin nile, Ọmọwe Ajibola Basiru sọ pe ile aṣofin ko lẹbi lori bi o ṣe buwọlu iyansipo Pantami gẹgẹ bi minisita.

Ọmọwe Basiru ṣalaye pe ko si ẹni to mu ẹjọ tabi ẹsun kankan wa lati tako iyansipo Pantami lasiko ti ile n ṣayẹwo awọn orukọ ti Buhari fi ṣowọ sawọn aṣofin.

”A ko ṣe ohun to lodi sofin, ko si ajọ eleto aabo kankan to sọ ohun kan nipa Pantami to le mu wa maa buwọlu iyansipo rẹ lasiko ti a n ṣe ayẹwo rẹ to fi di asiko yii.

Awọn sẹnẹtọ ko lagbara lati yọ minisita nipo, a kan le ṣe ayẹwo lasan an ni pẹlu ohun ti a ba mọ nipa awọn ti aarẹ fẹ yan sipo minisita.

Aarẹ nikan lo lagbara lati yan minisita si ipo, oun naa lo si lagbara lati yọ minisita to ba yan si ipo kuro nipo.

A ko le titori ohun tawọn eeyan n sọ lori ayelujara lati gbe igbesẹ kan tabi omiran,” Sẹnẹtọ Basiru ṣalaye.

Alaga igbimọ eto iroyin nile aṣofin agba sọ pe ko si ẹni to le tọka si ibi ti ofin ti sọ pe ile le yọ Pantami nipo ninu gbogbo awọn to n sọrọ lori ayelujara.

O ṣalaye pe Pantami ko tapa si ofin Naijiria lọna kọna, notiri idi eyi lawọn aṣofin ko le fi yọ nipo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…