Home ÀKỌ̀TUN Ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria, Aláàfin àti Oọ̀ni bẹnu àtẹ́ lu ìjọba
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 3, 2021

Ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria, Aláàfin àti Oọ̀ni bẹnu àtẹ́ lu ìjọba

Ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria, Aláàfin àti Oọ̀ni bẹnu àtẹ́ lu ìjọba

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn oríadé méjéèjì yìí ló sọ èròngbà wọn níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kọkànléláàdọ́ta Ààrẹ Ọ̀nàkakanfò ilẹ̀ Yorùbá, Gani Adams.

Alaafin ni o ṣeni laanu pupọ pe awọn ajinigbe atawọn janduku n ṣọṣẹ lai si idiwọ kankan.

Kabiyesi wa ke si ijọba apapọ lati wa ojutu si ọrọ eto abo naa ki awọn olugbe guusu iwọ-oorun Naijiria le wa ni alaafia.

O ni awọn ajinigbe atawọn janduku n jaye fa mi lẹsẹ ki n tutọ ti ijọba ko si ri nnkan ṣe sii.

Ọba Adeyemi tun ki Iba Gani Adams fun iṣẹ takuntakun to n ṣe ki ominira ilẹ Yoruba le ṣeeṣe, bẹẹ lo tun ni ki ijọba ji giri si eto abo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọlọrun ati iṣẹ ọwọ rẹ lo yan Gani Adams si ipo to wa, o gba mi n nnkan bii ọdun marun ati ọpọ etutu pẹlu ifọwọsowọpọ awọn alalẹ ki wọn to yan si ipo to wa.”

“Ko du ipo naa, ori lo gbe e de ipo ọhun, adura mi si ni pe yoo ko awọn iran Yoruba jẹ pẹ.”

Ẹwẹ, Ọọni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi sọ pe awọn ori ade nilẹ Yoruba yoo maa ṣatilẹyin fun gbogbo akitiyan lati daabo bo awọn eeyan ilẹ naa.

Nigba to n sọrọ, Gani Adams rọ ijọba apapọ lati rii daju pe aabo to peye wa fun awọn eeyan ilẹ Yoruba lapapọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…