Home ÀKỌ̀TUN Ilé ayé ò se é dá gbé – Chief Imam Ibafo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 2, 2021

Ilé ayé ò se é dá gbé – Chief Imam Ibafo

Ile aye o see da gbe – Chief Imam Ibafo
Ni gbogbo ojo ti awe ba ti bere ni As-Sheik Yusuf Abdul-Qodri Kelani pelu awon Aafaa to ku ti maa n jade, lati Mosalasi kan si omiran.
Eyi naa lo mu won gbe waasi naa de Mosalasi Ridwanullahi to wa ni adugbo Liberty estate, Ibafo. Waasi naa bo si igba ti awe pe mokandinlogun.
Eko po ninu ohun ti Al-Sheik Mufassir fi se waasi, Lara awon eko naa ni bi eniyan se le gbe aye ti ko ni dina Aljanna re. Baba je ki o ye gbogbo eniyan pe “ile aye ko se e da gbe”.
Baba je Ki o ye wa pe Olorun nikan ni o je eyokan ti o le da aye ati orun dari. Baba ni awa eniyan ti a ro pe a je eyokan gan an kii se eyokan nitori naa ni oju wa fi pe meji ti eti pe meji ti iho imu pe meji ti apa pe meji ti ese pe meji ti eti pe meji ati bee bee lo.
Bi chief Imam se n salaye yii ni awon eniyan bere si ni gbe Olorun tobi nipa sise “Allhau Akbar “. Imam Mufassirje ki o tun ye wa pe opo eya ara ti a ko le fi oju lasan ri naa lo tun wa ninu wa ti won je meji meji.
Eyi si n tumo si iwa rere ati igbe aye alaafia. Baba ni oluranlowo ni a je fun ara wa. Baba ni awon ara adugbo wa gbogbo mo wa si eniyan gidi, a ko gbodo je eni ti o maa fi gbodo aye wa roju koko ti a ba fe wo Alijanna soose.
Baba ni oko gbogbo maa se daadaa si iyawo bee si ni iyawo ko gbodo ko iyan oko kere, amojuto awon omo naa je dandan bi agbara ba se mo.
Imam tun fi kun un pe gbogbo eni to ba le pa awon ofin Olorun yii mo ni orileede Naijiria, eni Olorun tooto ni iru eniyan bee nitori pe opo nnkan ti kii je ki esin pe ni o po ni Naijiria.
Baba ni Naijiria le ti maa wa ninu awe ti e ti maa ri obinrin to n rin ni ilaji ihoho. Ilu yii la ti maa ri obinrin to ko gbogbo aya soke ati bee bee lo. Imam wa ni gbogbo eni to ba wa le se amoju kuro yii je eni Olorun tooto. Baba tun je ko ye wa pe esin rorun lati sin ni awon ilu ti o je kikida Musulumi nitori pe iberu Olorun maa po. Oju Ko si ni ri irikuri.
Eye ki i fi apa kan fo ni Chief Imam ilu Ibafo fi waasi naa se, Lara awon Aafaa nla nla to tele baba wa ni As-Sheik Muftahidden Opeloyeru (baba igbeti), chief Mufassir ati bee bee lo.
Leyin waasi ni baba wa se adura fun awon omo ile kewu nitori pe awon ni ogo esin ati ojo iwaju orileede. Baba se adura fun awon obi, alagbato ati gbogbo ilu lapapo.
Alhaji, Dr. Ambali Gold to je Imam Mosalasi naa fi emi imoore han loruko jomon-on Ridwanullahi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…