Home ÀKỌ̀TUN Tinubu ṣàbẹ̀wò ẹ kú aráfẹ́rakù s’ílé olóògbé Odumakin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 7, 2021

Tinubu ṣàbẹ̀wò ẹ kú aráfẹ́rakù s’ílé olóògbé Odumakin

Tinubu ṣàbẹ̀wò ẹ kú aráfẹ́rakù s’ílé olóògbé Odumakin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé ikú kankan kò sí, àsìkò tí kóówá dá pẹ̀lú Èdùwà ni yóó fàdàgbá ayé rọ̀ tì sí jínyìn lálède ọ̀run. Àìsí mọ́ lòpin èèyàn ní dúníyàn.

Aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Bola Tinubu, ti sàbẹ̀wò sí ilé agbẹnusọ ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Yinka Odumakin tó di olóògbé ní ọjọ́ Sátidé.

Àwọn Ìròyìn kan sọ pé ibùdó ìyàsọ́tọ̀ tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn alárùn Covid-19 ni iléèwòsàn ìkọ́ṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó, LASUTH, ló kú sí.

Tinubu ti kọ́kọ́ sọ nínú àtẹ̀jáde kan lọ́jọ́ Sátidé pé kò sí bí wọn ó ṣe sọ ìtàn ìṣèjọba àwarawa ní Nàìjíríà láì dárúkọ Odumakin.

Nígbà ayé rẹ̀, Odumakin má a ń bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu Tinubu àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ olóṣèlú ní Nàìjíríà.

Ó ṣàpèjúwe Yinka Odunmakin gẹ́gẹ́ bí akínkanjú, olóòótọ́ àti olùfọkànṣìn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ẹ̀yà Yorùbá, àti orílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà.

Lára àwọn ipa tó ní Odumakin kó lásìkò rògbòdìyàn ‘June 12’ lẹ́yìn ti wọ́n wọ́gilé ìdìbò ọdún 1993.

Ó ní “bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò wa kò papọ̀ lórí ètò òṣèlú, kò sí ìdí kankan fún mi lá’ti ṣìyèméjì nípa òtítọ́ tó fi ṣe gbogbo nǹkan tó ṣe lókè èèpẹ̀.

Títí láé ni yóó sì jẹ́ àwòkọ́ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbé ìṣerere orílẹ̀-èdè rẹ̀ leke ju ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…