Home ÀKỌ̀TUN Agbébọn jí mọ̀lẹ́bí kan gbé l’Ondo, àwọn ara’ìlú gbarata
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 7, 2021

Agbébọn jí mọ̀lẹ́bí kan gbé l’Ondo, àwọn ara’ìlú gbarata

Agbébọn jí mọ̀lẹ́bí kan gbé l’Ondo, àwọn ara’ìlú gbarata

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí a bá n rìnrìn àjò, àdúrà ká mórídélé náà la ó kúkú máa ṣe ,ṣùgbọ́n kò dà bí ẹni pé àdúrà yìí jẹ́ fún àwọn ìdílé yìí, bí àwọn agbébọn kan ti palẹ̀ ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún ọ̀hún mọ́ láú nílúù Ajowa-Akoko, ní Ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá-Ìwọ̀-oòrùn Àkókó ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Iroyin ni awọn eeyan naa n rinrinajo lọ si Abuja lati Ajowa-Akoko, nibi ti wọn ti lọ ṣe ọdun Ajinde ki awọn ajinigbe ọhun to ka wọn mọ abala kan ti ko dara loju ọna naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn ji olori ẹbi naa, Ibrahim Olusa pẹlu iyawo atawọn ọmọ rẹ gbe loju ibọn laarin Ajowa-Akoko si Ayere ni ipinlẹ Kogi, wọn si ko gbogbo wọn lọ sinu igbo kijikiji.

Wọn ni awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi awọn ti wọn ji gbe lati beere miliọnu mẹwaa naira owo idande wọn.

Isẹlẹ naa si ti mu jinijini ba ọkan awọn eeyan ilu ọhun.

Ọkan lara awọn adari ilu naa, to tun jẹ alaga igbijmọ adari Ajowa-Akoko ana, Ajayi Bakare to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ijinigbe ati idigunjale n peleke sii lagbegbe ọhun nitori ọna ti ko dara ni iha ipinlẹ Kogi.

Ọgbẹni Bakare gba ijọba nimọran lati tun ọna naa ṣe ni kiakia lati le dẹkun iwa ọdaran lagbegbe ọhun

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja Yínká Àlàbí Olu ilu orileede Naijiria ni Ab…