Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Buhari yan Alkali ní adélé Ọ̀gá Ọlọ́pàá tuntun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 7, 2021

Ààrẹ Buhari yan Alkali ní adélé Ọ̀gá Ọlọ́pàá tuntun

Ààrẹ Buhari yan Alkali ní adélé Ọ̀gá Ọlọ́pàá tuntun

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ààrẹ Orílẹ̀ yìí Muhammadu Buhari ti yan Ìgbákejì Ọ̀gá ọlọ́pàá Usman Alkali Baba gẹ́gẹ́ bí adelé Ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun.

Eyi n waye gẹgẹ bi Muhammed Adamu to jẹ ọga awọn ọlọpaa ni Naijiria ti n mojuto iṣẹlẹ ikọlu to waye ni ọgba ẹwọn ipinlẹ Owerri.

Minisita fun ọrọ olọpaa, Maigari Dingyadi lo kede igbesẹ tuntun ti Ààrẹ ṣẹṣẹ gbe naa.

Ọdun 1963 ni wọn bi Alkali Baba Usman ni ipinlẹ Yobe.

O kawe gboye ni Fasiti Bayero to wa nilu Kano, ati Fasiti ilu Maiduguri.

Ọdun 1988 lo darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ti o si goke lati oye ASP di kọmiṣọna ọlọpaa ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ọdun 2013.

Ṣaaju iyansipo rẹ gẹgẹ bi Adele Ọga Agba ọlọpaa, oun ni oludari ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati iwadii iwa ọdaran..

Gbogbo awọn eto ẹkọṣẹ gbogbo to yẹ fun oye kọọkan to gba lo ṣe lori awọn isẹ iwadii, igbesumọmi ati kikoju iwa ọdaran gbogbo to fi mọ amojuto lilọ bibọ ọkọ.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ ọlọpaa lagbaye,bee ni o tun jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ jade nile ekọṣẹ omo-ogun lagbaaye International War College.

O figba kan ri jẹ igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna ati Abuja.

Alkali Usman yoo maa gbaṣẹ lẹyẹ-o-ṣọka lọwọ ọga agba olopaa, Mohammed Adamu to n fi ipo naa silẹ bayii.

Ni osu keji ọdun 2021 lo ti yẹ ki Mohammed Adamu o fi ipo naa silẹ, ṣugbọn Aarẹ Buhari fi kun iye ọjọ rẹ lori oye nigba naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…