Home ÀKỌ̀TUN Ọgbẹ́ ọkàn ńlá tó nira láti tètè gbàgbé n’ikú Yínká Odùmákin – Ọọ̀nirìṣà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 5, 2021

Ọgbẹ́ ọkàn ńlá tó nira láti tètè gbàgbé n’ikú Yínká Odùmákin – Ọọ̀nirìṣà

Ọgbẹ́ ọkàn ńlá tó nira láti tètè gbàgbé n’ikú Yínká Odùmákin – Ọọ̀nirìṣà

Orẹ Òtítọ́jù

Àrólé Odùduwà tó tún jẹ́ Ọọ̀ni ti lfẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ẹnìtàn Ògúnwùsì, Ọ̀jájá 11, ti ṣàpèjúwe Olóògbé Yínká Odùmákin gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ìtàn kò le gbàgbé ipa takuntakun tó kó nínú ọ̀rọ̀ Ìjọba tiwa-n-tiwa lórílẹ̀-èdè yìí.

Ninu ọrọ ibanikẹdun ti Akọwe iroyin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita ni kabiesi ti sọ pe iku ọkunrin naa ba oun lojiji, nitori o ku lasiko ti iran Yoruba, paapaa, orileede Naijiria, nilo rẹ ju.

O ni okele nla to nira lati gbe mi ni iku rẹ jẹ fun Ilẹ Oduduwa, nitori adari ilẹ Yoruba to ni ẹmi ikora-ẹni-nijaanu, to si jẹ akekaka kọlọrọ o gbọ lọkunrin naa lorileede yii.

Ọọni tẹsiwaju pe Odumakin sin iran Oodua lai dibajẹ titi to fi ku, o si mu ijọba tiwa-n-tiwa gbooro lorileede yii nipasẹ bo ṣe maa n ke fun idajọ ododo ati kijọba ṣe nnkan to tọ lai role apa kan da apa kan si, ti ko si mọ tara rẹ nikan.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ko bẹru ẹnikankan, Ọọni sọ pe Odumakin ko figba kankan gboju kuro lara ohun to ba ro pe ko dara to tijọba Aarẹ Buhari ba ṣe lai tiẹ ro ti ibaṣepọ to ti wa laarin wọn ri.

Ọọni Ogunwusi ni alafo nla ni iku ọkunrin naa fi silẹ, o si waa di dandan bayii lati tẹle ipa rere to ti la silẹ fun igbesi aye irọrun fun gbogbo awọn eeyan orileede Naijiria.

Kabiesi gbadura pe ki Ọlọrun tu iyawo oloogbe naa ninu, ko si fun awọn mọlẹbi rẹ lokun lati la asiko to lagbara yii kọja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…