Home ÀKỌ̀TUN Kò sí ẹni tó ń dúkòkò mọ́ wá látí fí ọdáràn sílẹ̀–Kọmísọ́nnà ọlọ́pàá Ọ̀yọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 5, 2021

Kò sí ẹni tó ń dúkòkò mọ́ wá látí fí ọdáràn sílẹ̀–Kọmísọ́nnà ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

Kò sí ẹni tó ń dúkòkò mọ́ wá látí fí ọdáràn sílẹ̀–Kọmísọ́nnà ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà ní àìlè sọ̀rọ̀,ni ìpìlẹ̀ orí tí kò fẹ́ bẹ́gbẹ́ pé jèrè àwùjọ.

Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko ti ni, ko si ẹni to n dunkoko mọ awọn lati fi afurasi ọdaran tabi apaniyan to wa ni panpẹ awọn silẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa naa fi sita ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu iroyin pe, ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe agbatẹru fun awọn ọdaran nipinlẹ Oyo.

Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu akọroyin, lo ti fẹsun kan awọn agbofinro pe wọn kọ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn araalu lati so okun aabo ilu le dan-in.

Bakan naa ni Alaafin tilu Oyo Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta ti ke gbajare sita lasiko to gbalejo Oluwo tilu Iwo pe awọn ọlọpaa ma n tu afurasi ọdaran ti wọn ba fa le wọn lọwọ silẹ.

Gani Adams ni ihuwasi awọn agbofinro fihan pe, wọn ko mu isẹ wọn lọkunkundun lati dẹkun ipenija abo ni ilẹ Yoruba.

O wa sapejuwe bi ọlọpaa se mu mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC si ahamọ, lẹyin ti wọn fi panpẹ mu Wakili, afurasi Fulani ti wọn ni o n da awọn eeyan oke Ogun laamu.

Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni, gbogbo awọn afurasi ti awọn fi panpẹ mu ni awọn ti gbe lọ si ile ejọ lati Oṣu Kẹta, ọdun 2021, papa a awọn ti ẹsun wọn ni-in ṣe pẹlu ẹsun iditẹ mọ ijọba, ipaniyan, ijinigbe ati ole jija.

Lara awọn ẹsun ti wọn gbe lọ si ileẹjọ ni igbẹjọ laarin kọmisọnna ọlọpaa ati Abdulahi Yakubu Wakili, Kọmisọnna ọlọpaa ati Lawal Oseni ati Aliyu Oseni, pẹlu ti kọmiṣọnna ọlọpaa ati Ayuba Tukur.

”Igbẹjọ Abdulahi Yakubu yoo waye ni ọjọ kẹtadinlogun osu Karun, ti Lawal Oseni ati Aliyu Oseni waye ni ọjọ kọkandinlogun osu Karun nigbati ti Ayuba Tukur yoo bẹrẹ ni ọjọ Kẹrindinlgbọn osu Karun ọdun 2021.”

Kọmisọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko ni, o da awọn loju pe idajọ otitọ yoo leke ninu gbogbo igbẹjọ to wa ni iwaju awọn.

Nitori naa ,ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fi da awọn araalu loju pe, awọn n ṣiṣẹ awọn bi iṣẹ lai si ibẹru tabi ifoya.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja Yínká Àlàbí Olu ilu orileede Naijiria ni Ab…