Home ÀKỌ̀TUN Ọkọ̀ panápaná ò ráàyè wọnú ọjà torí àwọn ìsọ̀ tí wọ́n kọ́ dí ojú ọnà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 4, 2021

Ọkọ̀ panápaná ò ráàyè wọnú ọjà torí àwọn ìsọ̀ tí wọ́n kọ́ dí ojú ọnà

Ọkọ̀ panápaná ò ráàyè wọnú ọjà torí àwọn ìsọ̀ tí wọ́n kọ́ dí ojú ọnà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Se ni ariwo ẹkun gbalẹ kan, ti ọpọ eeyan si n kawọ lori lati se itara aje nitori bi ọpọ ọja se n jona ni ọja isọ paati ọkọ to wa ni Agodi Gate, nilu Ibadan.

A ri gbamu pe ọpọ sọọbu ni wọn ti kọ di awọn oju ọna to yẹ ki ọkọ maa gba laarin ọja naa, eyi to mu ko nira fawọn ọkọ panapana lati ri aaye wọnu ọja.

Ọpọ sọọbu ti awọn ẹya ara ọkọ olowo iyebiye wa lo jona kanlẹ ninu ijamba ina naa to bẹrẹ ni deede aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti.

Ọkan lara awọn to n sowo paati ara ọkọ ninu ọja nibẹ,Ọgbẹni Nurudeen Akintayọ fi aidunu rẹ han
nigba to n ba akọroyin sọrọ pe, adanu nla gbaa ni ati pe aanu Ọlọrun nikan lo ṣẹku fun ohun
bayii, tori oun o mọ ibo
ni oun yoo tun ti bẹrẹ.

” Ni nnkan bi aago kan oru ni mo gba ipe pe sọọbu n jona, n ko ti ẹ mọ kin laa mu, mo sa bẹ jana ni ti mo fi de bẹ, amọ ofo ti ṣe dukia jina”

Titi di akoko yii, awọn alasẹ ko tii mọ ohun to sokunfa ijamba ina naa awọn ,awọn eeyan kan salaye pe ina ọba ti wọn mu de lojiji lo fa ijamba ina ọhun.

Iroyin ti ẹ fi ye wa pe ọja naa ko ri ina ọba lo fun aimọye ọdun, ki wọn to mu ina pada wa sibẹ.

A gbọ pe abala ti wọn ti n ta taya ọkọ ni ina ọhun ti rinlẹ julọ.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn osisẹ panapana de sibi isẹlẹ naa lati bomi pa ina ọhun amọ o nira fun won lati ri ọna de ibi ti awọn ina ọhun ti n jo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…