Home ÀKỌ̀TUN Aṣòfin Nàìjíríà, Haruna Maitala, ọ̀mọ̀ rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì pádánú ẹ̀mí lójijì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 4, 2021

Aṣòfin Nàìjíríà, Haruna Maitala, ọ̀mọ̀ rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì pádánú ẹ̀mí lójijì

Aṣòfin Nàìjíríà, Haruna Maitala, ọ̀mọ̀ rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì pádánú ẹ̀mí lójijì

Ọrẹ Òtítọ́jù

Asofin to n soju ẹkun ariwa Jos/Bassa ni Ile Aṣojusofin Naijiria, Haruna Maitala ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ.

Ijamba ọkọ naa waye ni opin ọsẹ lasiko to n rin irinajo lọ ni opopona ilu Abuja si ilu Jos.

Asofin naa ku pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn oṣiṣẹ rẹ meji lasiko ti wọn n lọ fun igbeyawo ọmọ rẹ ọkunrin ni ilu Jos.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Asofin naa, Josẹph Adudu fi sita ni ijamba ọkọ gbigbona naa lo mu ẹmi aṣofin Haruna Maitala lọ.

Bakan naa lo fi kun un wipe opin ọṣẹ naa ni wọn sin in ni ọna ẹsin musulumi

Lẹyin naa ni awọn olubaṣiṣẹ rẹ ati awọn akẹgbẹ rẹ ti n ṣedaro rẹ.

Wọn ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan, to fẹran araalu to si gbe igbe aye irẹlẹ lasiko to wa l’okeepe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja Yínká Àlàbí Olu ilu orileede Naijiria ni Ab…