Home ÀKỌ̀TUN YCE, Afenifere ní àdánù ńlá ni ikú Odùmákin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 3, 2021

YCE, Afenifere ní àdánù ńlá ni ikú Odùmákin

YCE, Afenifere ní àdánù ńlá ni ikú Odùmákin

Orẹ Òtítọ́jù

Ọpọ ọmọ ilẹ kaarọ oojire lo ti n sedaro iku agba ọmọ Yoruba to jade laye, Oloye Yinka Odumakin.

Ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH ni Odumakin dakẹ si lasiko aisan ranpẹ to se e.
Gẹgẹ ba se gbọ, ẹka ile iwosan naa, ti wọn ti n tọju awọn eeyan to ni arun Coronavirus ni Odumakin mi kanlẹ si ni idaji ọjọ Abamẹta.

Ọjọgbọn Banji Akitoye sọ fun akoroyin pe akikanju ọmọ Yoruba lo papoda yii, igi nla lo da nigbo.

Lero ti akọwe fun ẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba, YCE, Dokita Kunle Olajide ni “Iku doro, erin wo, igi da, Ajanaku sun bi oke, ẹni re lọ.”

Dokita Olajide ni alafo nla ni iku Odumakin yoo fi silẹ ninu iran Yoruba nitori ipa akikanju to ko fun ilọsiwaju iran rẹ lasiko to wa loke eepẹ.

Akọwe ẹgbẹ agbaagba fun ilẹ Yoruba naa wa gbadura pe ki ọba oke tẹ Odumakin si afẹfẹ rere.

Ninu ọrọ ti e ,akọwe ẹgbẹ Afenifere, Basorun Sehinde Arogbofa se apejuwe iku Odumakin bi adanu nla fun ẹgbẹ naa ati Orílẹ̀ yìí lápapọ̀.

Arogbọfa ni iku Odumakin ba oun lojiji, to si jẹ ẹsẹ nla to ba oun lairotẹlẹ nitori ẹni to sun mọ oun bii isan ọrun ni.

“Yinka ko ba ma lọ lasiko yii nitori ọlọpọlọ pipe ẹda ni, to si maa n mu awọn aba to kun fun ọgbọn wa, isẹlẹ yii ba mi ninu jẹ pupọ.

Arogbofa wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe Yinka Odumakin si afẹfẹ rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…