Home ÀKỌ̀TUN Ó ṣeéṣe kí n gbégbá ìbò lọ́dún 2023–Muyiwa Ademola
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 2, 2021

Ó ṣeéṣe kí n gbégbá ìbò lọ́dún 2023–Muyiwa Ademola

Ó ṣeéṣe kí n gbégbá ìbò lọ́dún 2023–Muyiwa Ademola

Orẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní n tó wuni, níí pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni .
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà n-nì, Muyiwa Ademola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Muyi Authentic.

Muyiwa Ademola lo kede loju opo Sítágíràmù rẹ pe oun ti setan lati dara pọ mọ agbo oselu ilẹ wa, ti oun yoo si gbegbe ibo lọdun 2023.
Ademola ni oun yoo sinmi diẹ naa fun ere tiata, ti oun yoo si kọju mọ oselu sise gẹgẹ bo se wa ninu erongba oun lati ọjọ pipẹ wa.
Bakan naa ni ilumọọka osere tiata naa ni oun ti pinnu lati dije fun ipo asofin agba ta mọ si Sẹ́nétọ̀ ninu idibo gbogbo gboo lọdun 2023.

Ademola ni “Isisẹ sin ọmọniyan ni owo ile to san pe o n gbe ile aye, gẹgẹ bi Muhammed Ali ti wi. Lẹyin o rẹyin, mo ti wa n jade sita bayii lati sisẹ sin orilẹede mi atawọn eeyan mi.

“Mo n yẹba diẹ na fun isẹ tiata sise lati dije fun ipo Sẹnetọ, ki Ọlọrun ran mi lọwọ”

Ademola ni ilu Ibadan ni oun tẹdo si, fun ọdun mẹtadinlaadọta amọ ọmọ ọba ni oun ni ididle ọba kan nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.

Gbajumọ osere tiata naa wa n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe nibo ni wọn lero tabi ti wọn le gba oun nimọran lati dije fun ipo naa.

O ni se ilu Ibadan lo yẹ ki oun ti dije ni abi Abeokuta tii se ilu abinibi oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé

Àwọn ọ̀tá Orílẹ̀ yìí kan ló n mìjọba mi lògbòlògbò bíi kó dojúdé Ọrẹ Òtítọ́jù Sé àwọn àgbà…