Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Ìtọpinpin àwọn oníròyìn ló jẹ́ kí wọ́n rí Profeṣsor Peller pa – Iyawo opidan naa

Ìtọpinpin àwọn oníròyìn ló jẹ́ kí wọ́n rí Profeṣsor Peller pa – Iyawo opidan naa

Alhaja Silifa Abiola Peller, eni to je iyawo Oloogbe Abiola Peller, ti se alaye bi awon aalagbapa (hired killers) se ri bale oun pa.
Won ni ‘E mu u, e ki I, eranko bee ko ni oore.’
Opidan ti gbogbo aye mo si Professor Peller naa ki se eni kan ti won kan le ri pa bee bi eni pa adie.
Ere lo ba edun nile ti edun ko mo o sa lojo oju ogun le, tori ere ori igi lo mo edun lara.
Lori awo, nibi to ti n kirun ni awon adigunjale naa pa a mo.

Lady Peller ati oko re
Ninu iforowanilenuwo kan pelu BBC, Iyaafin Peller ni itopinpin awon oniroyin gan-an lo da wahala sile.
O ni awon oniroyin lo maa n bi Professor Peller laidake pe asiko wo lo maa n tura sile.
O ni bale naa wa so fun won pe igba ti oun ba n kirun ni, ti oun wa niwaju Olorun Oba oun.
Iyaafin Peller ni eyi ni awon osika gbo ti won fi kogun ja alasiko to n kirun.
Lady Peller ni oun ati okunrin naa nifee ara awon denu, to si je pe ife naa si wa lokan oun doni olonii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…