Home LÁGBO ÀRÍYÁ Àìlera kan bá mi làsìkò tí mo gbé IJÓ YÓYÒ jáde – Kollington Ayinla
LÁGBO ÀRÍYÁ - orisiirisii - Orisirisi - March 22, 2021

Àìlera kan bá mi làsìkò tí mo gbé IJÓ YÓYÒ jáde – Kollington Ayinla

Osere fuji pataki, Alhaji Kollington Ayinla, ti so asiri kan lori orin re kan to laluja, iyen IJO YOYO.
Opo eniyan lo gba pe orin naa lo gbayi julo, ti o si je pe o si maa n dun leti di oni olonii.
Bakan naa ni fidio orin naa lagboro, nibi ti Iyabode ti n tadi reke pelu Kollington.
Ti a ko ba gbagbe, akorin pataki yii fe Iyabode niyawo, sugbon obinrin naa ko pe to fi di oloogbe, lasiko ti ile Kollington jo ni Alagbado, ko to di pe o fi se ile oba to jo,ewa lo bu kun un.
Lasiko ti onifuji naa n foro jomitoro oro pelu iwe iroyin VANGUARD lojo die seyin, o ni ailera kan se oun lasiko ti awo IJO YOYO jade.
Bi o tile je pe Kollington ko so hulehule aisan naa, o tumo si pe ko ni le je gbogbo mula ti kiba je lasiko naa, to ba se pe ara re le daadaa ni.
Idi ni pe iru awo orin to ba gbalukan naa maa n mu owo wa, ti won yoo maa pe akorin naa nibi gbogbo.
Osere ti a mo si Bata Fuji King, Baba Alatika, Kebe n Kwara ati Professor Master naa wa so fun awon oniroyin pe ohun kan ti oun kabamo ni pe oun ko lo si yunifasiti.
Sugbon o ni inu oun dun pe awon omo oun lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…