Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari
Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ààrẹ Muhammadu Buhari ni yóò túbọ maa wo ojú Ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà Olúṣẹ́gun fún ọgbọ́n ìmọ̀ àti òyè ni.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àgbà fún Ààrẹ Buhari lóri ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́, Garba Shehu ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fọ́wọ́ si láti kí Ọbasanjọ́ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin.
Àtẹ̀jáde náà ni ” Ààrẹ Muhammadu Buhari bá Ààrẹ àná Olúṣẹ́gun Obásanjọ́ yọ̀ fún ayẹyẹ ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin”
” Lórúkọ ìjọba Nàìjíríà , ààrẹ Muhammadu Buhari gbàdúra pé ààrẹ to ti sin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ìfẹ́, ìfọkànsìn, àti ìfarajì tẹ̀síwájú láti má wa lori èèpẹ̀ ilẹ̀ ní àláfíà àti ìdùnú
“Ààrẹ Buhari ni orílẹ̀-èdè yìí yóò túbọ̀ máa gbójú sókè fún ìmọ̀ àti ìfọ̀kànsìn.
Bákan náà ni Ààrẹ gbàdúrà kí Èdùà lọ́ra ẹ̀mí rẹ̀ kí ó lè pé fún orílẹ̀ èdè yìí.
Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?
Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …