Home ÀKỌ̀TUN Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Kófíídì-19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 6, 2021

Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Kófíídì-19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria

Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Kófíídì-19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria

Ọrẹ Òtítọ́jù

Abẹrẹ ajẹsara covid 19 lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ti de si orilẹede Naijiria.

Ilu Abuja ni ọkọ ofurufu to gbe abẹrẹ ajẹsara naa balẹ si, awọn eleto ilera si wa nibẹ lati rii pe gbogbo rẹ lọ daradara.

Nibayii, Ijọba ti ni awọn eleto ilera ni yoo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara naa.

Ti awọn oloṣelu yoo si bẹrẹ si ni gba lati Ọjọ Ajẹ, ọṣẹ too n bọ.

O ti le ni ẹgbẹrun eniyan ti arun Coronavirus ti mu ẹmi wọn lọ lorilẹede Naijiria.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ilera alakọbẹrẹ, iyẹn National Primary Health Care Development Agency, NPHCDA, ti kede bi awọn ṣe le gba abẹrẹ naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn, NPHCDA ni awọn eeyan le lọ fi orukọ silẹ lati gba abẹrẹ naa lori ikanni www.nphcda.gov.ng
Nibẹ ni koowa yoo ti lanfaani ati fi awọn iroyin nipa wọn sinu fọọmu ọhun.
Lẹyin naa ni wọn yoo funwọn ni ami idanimọ ti wọn yoo fi lanfaani si abẹrẹ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …