Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 6, 2021

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ọrẹ Òtítọ

Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Naijiria ni abẹrẹ naa.

Ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ni Ààrẹ ati igbakeji rẹ ti gba ti wọn, wọn si ṣafihan eto naa lori amohunmaworan.

Aarẹ Buhari sọ pe bi oun ṣe gba abala akọkọ abẹrẹ naa, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ni ẹtọ lati gba, ki awọn naa ṣe bẹ ẹ.

Ọga agba ajọ eto ilera alabọde ni Naijiria, Dokita Faisal Shuaib sọ pe ireti wa pe bi Ààrẹ ṣe gba abẹrẹ ajẹsara naa yoo ṣe iwuri fun awọn araalu lati gba fun idaabo bo lọwọ Covid-19.

Ọjọ Aje ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ Aarẹ Buhari yoo bẹrẹ si ni i gba, gẹgẹ bi ikede ti Dokita Shuaibu fi sita.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …