Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí ìforúkọsílẹ̀ síìmù jákèjádò ìjọba ìbílẹ̀ ní Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 3, 2021

Ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí ìforúkọsílẹ̀ síìmù jákèjádò ìjọba ìbílẹ̀ ní Nàìjíríà

Ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí ìforúkọsílẹ̀ síìmù jákèjádò ìjọba ìbílẹ̀ ní Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní kò sí ohun tó le koko tí kìí rọ̀, Ìjọba àpapọ̀ ti fún àwọn iléeṣẹ́ ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láṣẹ láti ṣe àgbékalẹ àwọn ọọfisi tí wọ́n ti lè máa pààrọ̀ síìmù fún àwọn èèyàn ní gbogbo Ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní Nàìjíríà.

Bẹ́ẹ̀ ni Ìjọba àpapọ̀ tún ṣe àfikún iye àkókò tí àwọn tó ń fi orúkọ síìmù sílẹ ní àṣẹ láti máa ṣe iṣẹ́ náà láti ọdún kan si ọdún márùn ún.

Àfikún yìí ni Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tó ń rí sí ọ̀rọ̀ Ìforúkọsílẹ̀ síìmù buwọ́lù nílùú Àbújá.

Alága ìgbìmọ̀ náà, mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Ọ̀mọ̀wé Isa Ali Ibrahim Pantami sọ pé Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbésẹ̀ ọ̀hún lọ́nà àti mú ayé dẹrùn fún àwọn èèyàn ìlú.

Pantami ṣàlàyé pé ojúṣe Ìgbìmọ̀ ọ̀hún ni láti gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ fún Ìforúkọsílẹ̀ síìmù.

Mínísítà ọ̀hún gbóríyìn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà fún sùúrù wọn lẹ́yìn tí Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ tuntun lórí síso síìmù pọ̀ mọ́ nọ́ńbà Ìdáni mọ̀ NIN.

Lẹ́yìn náà ló fi dá àwọn èèyàn ìlú lójú pé gbogbo ìgbésẹ̀ Ìjọba àpapọ̀ láti àkókò yìí lọ yóó jẹ́ èyí tí yóó mú ayé dẹrùn fún wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …