Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ò padà sílé ẹ̀kọ́ wọn ní Kagara mọ́ torí àwọn ajínigbé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 28, 2021

Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ò padà sílé ẹ̀kọ́ wọn ní Kagara mọ́ torí àwọn ajínigbé

Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ò padà sílé ẹ̀kọ́ wọn ní Kagara mọ́ torí àwọn ajínigbé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Iroyin ko to amojuba lẹnu awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama ilu Kagara nipinlẹ Niger to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ awọn ajinigbe lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 2021.

Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello lo tẹwọ gba awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa ti gbogbo wọn jẹ mejildinlogoji.

Ọkan lara awọn akẹkọọ naa Abubakar Sidi, ọmọ ogun ọdun to wa ni kilaasi SS3 ṣalaye pe awọn janduku ajinigbe ọhun fiya jẹ awọn nipasẹ iṣẹ ti obi ẹni kọọkan awọn n ṣe.

”Wọn ko fun wọn lounjẹ lati ago kan ọsan to fi di oru ki wọn to pada fun wa lounjẹ.

Lẹyin ti wọn fun wa lounjẹ tan, wọn bẹrẹ si ni sọ fun wa pe ki awọn ti baba wọn ba jẹ ọlọpaa ati sọja bọ sita, eyi lo maa sọ iru iya ti wọn maa fi jẹ wọn,” Sidi ṣalaye.

Akẹkọọ miran, Suleiman Lawal toun naa wa ni kilaasi SS3 ṣalaye pe ”awọn ajinigbe fiya jẹ wa debi pe n ko ro pe mo le pada si ilẹ ẹkọ wa mọ.”

Awọn akẹkọọbinrin to wa lara awọn akẹkọọ naa ko tiẹ le sọrọ rara fun ẹru to si wa lara wọn.

Ọpọ awọn obi to ba awọn akọroyin naa sọ pe awọn le maa jẹ ki awọn ọmọ awọn pada si ile ẹkọ naa mọ.

Arabinrin Elizabeth Jonathan to jẹ ọkan lara awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn jigbe ni oun ko le sun fun ọjọ mọkanla tawọn akẹkọọ naa fi wa lakata awọn ajinigbe.

”Ayọ mi kun wi pe ọmọ mi ti kuro lọwọ awọn ajinigbe, ko ni pada si ile ẹkọ naa mọ,” Arabinrin Jonathan lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, Gomina Bello ipinlẹ Niger ti kede pe ijọba n gbero lati gbe awọn ile ẹkọ tawọn akẹkọọ n sun ti pa.

Gomina ipinlẹ Niger sọ pe gbogbo eeyan mejidinlogoji ti wọn jigbe ni wọn ti gba itọju nile iwosan.

Gomina Bello fikun ọrọ rẹ pe ọkan lara awọn akẹkọọ mẹtalelogun to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ awọn ajinigbe si tun wa nile iwosan tori ailera rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …