Home ÀKỌ̀TUN Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 27, 2021

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Orẹ Òtítọ́jù

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pàkan ní òmí-ìn ń rú tú bíi iná inú ẹ̀ẹ̀rùn.
Àwọn ajinigbepawo tun ti ṣọṣẹ ijinigbe ni ilu Jangebe ipinlẹ Zamfara.

Akẹkọọbinrin ni wọn tun ji gbe lọtẹ yii, wọn o si kere niye rara. Ṣaaju, iye ti wọn kọkọ sọ ni pe ọọdunrun ọmọbinrin ni wọn ti ji gbe.

Ko tii si aridaju kankan nipa awọn to ji awọn akẹkọ naa gbe bẹẹ si ni ko sẹni to mọ ibi ti wọn gbe wọn lọ.

Ẹwẹ, awọn ti o bá akọ̀ròyìn sọrọ sọ pe o daju wipe o le lọọdunrun awọn ọmọbinrin naa ti wọn jigbe nileewe ni Zamfara.
Baba ọkan lara awọn akẹkọ naa ati olukọ ni ileewe ọhun sọ pe lootọ ni o ṣẹlẹ.

Oṣojumikoro sọ nigba ti wọ́n fi ka iye awọn ọmọ ile iwe naa to ku nilẹ ni wọn ri i pe irinwo lawọn ti wọn ko ri.

Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria naa royin rẹ pe Kọmisọna eto abo nibẹ, Abubakar Dauran sọ pe ọgọgọrun awọn ọmọ ileewe ni awọn agbebọn ti ji gbe l ṣugbn ti ko sọ iye wọn pato ni tirẹ.

Eyi waye ni ko pẹ ti akitiyan ṣi n lọ lọwọ lati doola awọn akẹkọọ Kangara ti wọn ṣẹṣẹ ji gbe lọsẹ to kọja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá k…