Home ÀKỌ̀TUN Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 25, 2021

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwáyé è kú ò sí, gbogbo wa laó padà sálákeji bọ́jọ́ tí kóówá wá dà bá ti pé.

Poro po ro lomi ẹkun n da a jade lẹyinju awọn eeyan nibi itẹ oku National Military Cemetery l’Abuja nibi ti ile iṣẹ ologun Naijiria ti n si oku awọn meje to rajo alọọde, ninu baalu to ja lọjọ Aiku.

Awọn Sagẹnti naa wa lara awọn to wa ninu ọkọ baalu Beechcraft King Air 350 ti ile iṣẹ ogun ofurufu eyi to ja ni ilu Bassa ti ko jina si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ti Abuja lasiko ti wọn lọ fun iṣẹ ogun kan.
Lara awọn to wa nibi eto isinku naa ni Minisita eto abo, Bashir Magashi, awọn ọga awọn ologun mii ti ọga awọn ọmọ ogun alaabo, Major General Lucky Irabor dari.

Awọn mọlẹbi awọn oloogbe naa wa nibi itẹ oku nibi ti ko ti si oju ẹni kankan to gbẹ tabi da furu ayafi pẹlu omije tori awọn ẹni ire to lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá k…