Home ÀKỌ̀TUN Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí Ààrẹ Buhari yàn sípò, aṣojú Nàìjíríà ní òkè òkun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 24, 2021

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí Ààrẹ Buhari yàn sípò, aṣojú Nàìjíríà ní òkè òkun

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí ààrẹ Buhari yàn sípò, aṣojú Nàìjíríà ní òkè òkun

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà ní àgbájọ ọwọ́ la fií sọ̀yà.
llé ìgbìmọ̀ aṣofin ti buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí ààrẹ Buhari yàn sípò, Olonisakin, Buratai gẹ́gẹ́ bi aṣojú Naijiria ní òkò òkun.
Awọn ọgagun ti wọn buwọlu naa ni ọgagun Gabriel Olonisakin; ọgagun Tukur Buratai; ọgagun Ibok Ibas ati ̣ọgagun Abubakar Sadique.

Ọgagun Olonisakin ti jẹ́ adari ẹka ileeṣẹ Ologun Naijiria tẹlẹri, nigba ti Buratai je adari fun awọn ọmọ ogun ori ilẹ, ti Ibok Ibas si jẹ adari fun ikọ ọmọogun ori omi, ti ọgagun Sadique si jẹ adari tẹlẹ fun ikọ ọmọogun ofurufu.

Igbesẹ ile aṣ̣ofin yii waye lẹyin ọjọ marun un ti igbimọ aṣofin lori ọrọ ilẹ okeere ṣe ọfintoto lori wọn lẹyin ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari fi orukọ wọn sọwọ si ile aṣofin agba.

Ile igbimọ aṣofin ninu ọrọ wọn ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn igbimọ beere awọn ibeere lọwọ wọn to jọ mọ iṣẹ ti wọn ti ṣe tẹlẹri, ati awọn ipo ti wọn ti yan wọn si laipẹ yii.

Ijọba orilẹede Naijiria ni fifi orukọ wọn sọwọ si ile igbimọ aṣofin ba ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 mu.

Amọ igbimọ naa sọ pe awọn gba iwe ipẹjọ meji to tako iyansipo wọn, ti wọn si fi ọwọ osi daanu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …