Home ÀKỌ̀TUN Mo sun ìlú Ìbàràpá mọ́jú lẹ́yìn tí wọ́n pa Dókítà Abóròdé – Mákindé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 23, 2021

Mo sun ìlú Ìbàràpá mọ́jú lẹ́yìn tí wọ́n pa Dókítà Abóròdé – Mákindé

Mo sun ìlú Ìbàràpá mọ́jú lẹ́yìn tí wọ́n pa Dókítà Abóròdé – Mákindé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Wọ́n ní ohun tó pamọ́, kedere ló hàn sí Ọlọ́run Ọba.
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lori iku ọmọwe Fatai Aborode ti awọn janduku kan ṣekupa nipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sọrọ eto kan nileeṣẹ igbohunsafẹfẹ abẹlẹ kan niluu Ibadan, Makinde ni iku ọmọwe naa lọwọ oṣelu ninu.

Makinde sọ pe oloogbe ọhun jẹ ẹnikan to sun mọ ohun nitori naa oun ko le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iku rẹ.

O ṣalaye pe oun sun mọju nigba ti oun ṣabẹwo si ilu Ibarapa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ki oun le mo bi ọrọ naa ṣe jẹ ni pato.

Gomina ọhun ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n sọ pe awọn Fulani lo ṣekupa arakunrin ọhun, ṣugbọn nigba ti oun foju gaanni baba oloogbe naa, o sọ fun oun kedere pe ọrọ iku rẹ lọwọ oṣelu ninu.

Makinde ni baba oloogbe ọhun ṣalaye fun oun pe alupupu lo gbe lọ ọmọwe Aborode lọ si oko lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ, bo tilẹ jẹ pe Aborode ko pada wale mọ, ṣugbọn ko si ijamba kankan to ṣẹlẹ si ẹni to fi alupupu gbe lọ sinu oko.

O ni oun ti paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati gbe iwadii to tọ dide lati mọ irufẹ iku gan to pa oloogbe naa.

Gomina Makinde fi kun pe ki awọn ara ilu maa gbiyanju lati sẹ iwadii ohun gbogbo ti wọn ba gbọ ki wọn to maa sọrọ nitori awọn kọlọrọsi to maa n ti ọwọ oṣelu bọ irufẹ iṣẹlẹ bayii.

Makinde pari ọrọ rẹ pe kii ṣe awọn Fulani nikan lo n da ilu ru, awọn ọmọ ilẹ Yoruba naa wa nibẹ pẹlu.

Lẹyin naa lo kilọ fun gbogbo awọn to maa n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ki wọn ṣọra wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá k…