Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé pàṣẹ pe ki wọ́n sí ọjà Ṣaṣa
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 23, 2021

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé pàṣẹ pe ki wọ́n sí ọjà Ṣaṣa

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé pàṣẹ pe ki wọ́n sí ọjà Ṣaṣa

Ọrẹ̀ Òtítọjù

Ṣé kò sí n tó le koko tí kìí rọ̀,
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣèyí Mákindé ti pàṣẹ pé kí wọ́n ṣí ọja Ṣaṣa padà Lẹ́yìn ọsẹ mélòó kan tí wọ́n ti ọjà náà pa.

Makinde kede ọrọ yii lọjọ Iṣẹgun nibi ipade ti o ṣe ni gbọgan nla igbalejo “House of Chiefs” to n bẹ ni Agodi, ilu Ibadan pẹlu igun mejeeji ti o n ba ara wọn ja ninu ọja naa.Gomina ṣe alaye wi pe nitori eto ọrọ aje ati awọn nnkan mii to niṣe pẹlu ipinlẹ yii ni oun ṣe gbe igbesẹ naa.

O ni, “Ti a ba wo eto ọrọ aje ati bi nnkan ṣe ri fun wa, mo ti gbọ nnkan ti ẹ sọ, lẹsẹkẹsẹ si ni a o ṣi ọja naa pada. Wọn yoo gbe awọn ẹrọ itulẹ lọ si ọja naa lonii”.Makinde tẹsiwaju wi pe, “Lasiko ti emi ati awọn arakunrin mi ti o jẹ Gomina ṣe abẹwo si aafin Seriki Ṣaṣa, nigba ti a n rin kaakiri mo ṣe akiyesi wi pe awọn eeyan ti a ri nibẹ ati awọn eeyan ti a pade ni ọdọ Baalẹ ni inu wọn ko dun nitori pe ọna ati jẹ ti di mọ wọn”.”Ti ẹ ba wo ipinlẹ Ọyọ kodaa gan nigba ti arun Corona de gongo, mo kọ lati ti awọn ọja wa nitori mo mọ pe nnkan ti pupọ eeyan ba ri lonii ni yoo sọ boya wọn a ri ounẹ jẹ lọla”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …