Home ÀKỌ̀TUN Fásitì Adekunle Ajasin, tí iléẹ̀kọ́ náà pa
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 26, 2021

Fásitì Adekunle Ajasin, tí iléẹ̀kọ́ náà pa

Fásitì Adekunle Ajasin, tí iléẹ̀kọ́ náà pa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kí ojú má ríbi, gbogbo ará lóògùn rẹ̀, àti pé n tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí a tií ṣe é.
Àwọn aláṣẹ Fásitì Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko, ti pàṣẹ pé kí ileewe náà di títì pa ní kíákíá.

Nínú ìkéde tí Adelé Akọ̀wé Iléẹ̀kọ́ náà, Opeoluwa Akinfenwa fi síta lọ́jọ́ Àìkú, àwọn aláṣẹ sọ pé ìgbésẹ̀ náà wáyé nítorí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ṣe ìwọ́de.

Wọn sì ti fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ní gbèdéke aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Aikyu, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kínní, ọdún 2021, láti fi ọgbà Iléẹ̀kọ́ sílẹ̀.

Ìròyìn sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ọ̀dọ́ ìlú Akungba-Akoko tú jáde ní ọjọ́ Àìkú, láti fi ẹ̀hónú hàn nítorí ìjàǹbá ọkọ̀ akẹ́rù tó pa àwọn èèyàn lọ́jọ́ Sátidé.

Ìjàǹbá náà ni ìròyìn sọ pé ó wáyé lásìkò tí ọkọ̀ ńlá kan tó kó símẹ́ńtì tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ Dangote, sọ ìjánu rẹ̀ nù, tó sì yawọ àwọn ṣọ́ọ̀bù kan ní ẹ̀gbẹ́ Fásitì Adekunle Ajasin tó wà nílùú náà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì náà wà lára àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàǹbá náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…