Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ọ̀dọ́ kọlu àwọn òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn ní Tede
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 26, 2021

Àwọn ọ̀dọ́ kọlu àwọn òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn ní Tede

Àwọn ọ̀dọ́ kọlu àwọn òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn ní Tede

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́ ni pé àwọn ọdọ kan kọlu àwọn òṣìṣẹ́ àjọ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ọ̀gá àgbà Àjọ náà nípìnlẹ̀ náà, Ajagunfẹ̀yìntì Olayanju sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kínní, ọdún 2021 ni àwọn ọ̀dọ́ yìí kọlu àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ní Agọ-Arẹ lásìkò tí wọ́n ń rin ìrìnàjò lọ sí ìlú Tede.

Ó ní wọn kò bá wàhálà kankan pàdé nílùú Agọ-Arẹ, wọ́n jẹ́ kí wọ́n ó kọjá lẹ́yìn tí wọ́n sọ pé ìjọba ìbílẹ̀ Ìtẹ̀síwájú ni àwọn ti wá fún iṣẹ́ àkànṣe.

“Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé Tedé ,níṣe ni àwọn ọ̀dọ́ kan kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú àdá, ìbọn àti àáké.

Ó ní lóòótọ́ ni kò sí ẹni tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àmọ́ òṣìṣẹ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn méjì farapa púpọ̀, tí wọ́n sì wà ni ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run níléèwòsàn.

Bákàn náà ni wọ́n bá àwọn ọkọ àjọ náà ni Ìjọba ìbílẹ̀ Ìtẹ̀síwájú jẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…