Home ÀKỌ̀TUN IG pàṣẹ kí Kọmísọ́nnà Ọ̀yọ́ mú Sunday Igboho wà sí Àbújá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 24, 2021

IG pàṣẹ kí Kọmísọ́nnà Ọ̀yọ́ mú Sunday Igboho wà sí Àbújá

IG pàṣẹ kí Kọmísọ́nnà Ọ̀yọ́ mú Sunday Igboho wà sí Àbújá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá pátápáta iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti pàṣẹ pé kí Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, arábìnrin Ngozi Onadeko mú Sunday Igboho tó l’óùn ń jà fún ẹ̀tọ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá.

Agbẹnusọ Ààrẹ Buhari, Garba Sheu ló fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí eto Hausa kan tí wọ́n pè ní: ”Ra’ii Riga ”.

Ó ní òun ṣẹ̀sẹ̀ bá ọ̀ga ọlọ́pàá, Mohammed Adamu ṣọ̀rọ̀ tán ni tó sì ní òun ti pàṣẹ kí Kọmíṣọ́nnà Ọ̀yọ́ mú Ìgboho wá sí Àbújá.

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni orúkọ Sunday Igboho ti gbòde kan paàpá lórí ayélujára lẹ́yìn tó sàbẹ̀wò sí ìlú Ìgàngàn tó sì fi gbèdéke ọlọ́jọ́ méje lélẹ̀ fáwọn Fulani ìlú náà láti kúrò níbẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ló késí gbogbo àwọn Yorùbá ní Ọ̀yọ́ àti ìpínlẹ̀ míì láti gbérasọ takò àwọn Fulani ọ̀daràn ajínigbé tó ń da omi àlàáfíà ilẹ̀ Yorùbá rú.

Malam Garba Shehu ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ àwọn tó ń da omi àlàáfíà ìlú rú jẹ́ ìpèníjà fún Ìjọba nítorí bí àwọn tí wọ́n láwọn ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn yí ṣe ń kọdí ìjọba.

Ó ní àṣẹ tó wà nílẹ̀ láti ọdọ ọ̀ga àgbà ọlọ́pàá ní pé kí wọ́n gbé Sunday Igboho lọ sí Àbújá ki, wọ́n sì lọ ṣẹjọ́ rẹ̀ níbẹ̀.
Ṣaájú ní ọṣẹ yí ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú náà ti fún àwọn darandaran Fulani lọ́jọ́ méje kí wọ́n kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ náà.

Ọ̀rọ̀ yìí dá fákínfà sílẹ̀ ti Ààrẹ Buhari sì kìlọ̀ fún un láti má ṣe dán-an-wò.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…