Home ÀKỌ̀TUN Seriki Fulani ké gbàjarè, ẹ dákun ẹ báwa bẹ Sunday Igboho
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 21, 2021

Seriki Fulani ké gbàjarè, ẹ dákun ẹ báwa bẹ Sunday Igboho

Seriki Fulani ké gbàjarè, ẹ dákun ẹ báwa bẹ Sunday Igboho

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ ń bèèrè lásìkò yìí ni pé kín ní yóó ṣẹlẹ̀ báyìí tí àsìkò ẹ káàásá yín kúò ń lẹ̀ yí ọ̀hún tí ń ku bíi wákàtí díẹ̀ sí àsìkò tí gbèdéke ọjọ́ méje tí èèkàn ọmọ Yorùbá n nì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ, ti ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho fún àwọn Fulani lágbègbè Ìbàràpá
yóó pé.

Séríkí Fulani ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alhaji Abdulkadir ti ké gbàjarè síta pé ẹnikẹ́ni tó bá mọ Olóyè Sunday Igboho kó bá àwọn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síi nítorí pé kò sí ibi tí àwọn leè kó lọ báyìí mọ́ lẹ́yìn àádọ́ta ọdún.

Alhaji Abdulkadir tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé gbogbo ibi tó yẹ làwọn ń sá káàkiri lọ báyìí láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ọ̀rọ̀ náà.
Ó ní lóòótọ́ Ìjọba ń fi àwọn lọ́kàn balẹ̀ pé Sunday Igboho kò ní leè ṣe ohun tó wí síbẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tó bá mọ̀ ọ́n làwọn ń bẹ̀ báyìí ki wọ́n bá àwọn pẹ̀tù síi nínú kí wọ́n sì le jókòó ṣọ̀rọ̀ náà ní ìtùbí ìnùbí.

Alhaji Abdulkadir tó ní bí àwọn alétílápá darandaran tó sọ ara wọn di dáràrandaràn náà ṣe ń sọsẹ́ fún àwọn ọmọ onílẹ̀ lágbègbè náà ni wọ́n ń sọsẹ́ fún àwọn gan an pẹ̀lú tó jẹ́ Fulani tẹ̀dó sí agbègbè náà

Séríkí ní àwọn ti kàn sáwọn agbófinró, àwọn ṣì ti kàn sáwọn ọbalayé lágbègbè Ibarapa láti leè wójútùú sí ọ̀rọ̀ náà, tó sì jẹ́ pé wọ́n ń fi àwọn lọ́kàn balẹ̀ ni pé yóó lójú tù ú láìpẹ́.

Ó ní àwọn kò palẹ̀mọ́ ẹrù kankan mọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn kò tilẹ̀ mọ ibi tí àwọn leè doríkọ nítorí pé agbègbè náà ni gbogbo àwọn mọ̀ ní ilé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ wọn ti gbé níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…