Home ÀKỌ̀TUN Ìròyìn òfegè lásán ni! Tinubu kò lùgbàdì Kòrónáfairọ̀ọ̀sì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 3, 2021

Ìròyìn òfegè lásán ni! Tinubu kò lùgbàdì Kòrónáfairọ̀ọ̀sì

Ìròyìn òfegè lásán ni! Tinubu kò lùgbàdì Kòrónáfairọ̀ọ̀sì

Fẹ́mi Akínṣọlá

A kìí fí ọ̀rọ̀ pápá lọ ẹja, Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀rí, Aṣíwájú Bola Tinubu ti sọ pé àhesọ làwọn kan ń gbé kiri pé òun ti kárùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ọ̀rọ̀ náà ti lu orí ayélujára pa pé Tinubu ti lùgbàdi Kófíìdì-19, ó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn l’órílẹ̀èdè Faransé lókè òkun.

Ṣùgbọ́n Tinubu tó gba ẹnu olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Tunde Rahman ṣọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ìgbà mẹ́ẹ̀dógún lòun ti ṣe àyẹ̀wò fún Kófíìdì-19 eléyìí tó sì já sí pé ṣáká lara òun dá.

Ọ̀gbẹ́ni Rahman ní irọ́ funfun báláú láti ọ̀run àpáàdì ni ìròyìn ọ̀hún.

”Koko lara Aṣíwájú le, kò sì sàìsàn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì” Rahman ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Rahman sọ pé lóòótọ́ ni Tinubu kò sí ní Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé pé ilẹ̀ Faransé kọ́ ni Aṣíwájú wà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ṣe sọ lórí ayélujára.

”Ìlú London ni Tinubu wà, kìí ṣe Orílẹ̀-èdè Faransé gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ṣe sọ lórí ayélujára,” Ọ̀gbẹ́ni Rahman ṣàlàyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…