Home ÀKỌ̀TUN Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ìbàdàn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 27, 2020

Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ìbàdàn

Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àfi kí Ọlọ́run ṣá má a dáàbò Rẹ̀ bò wá nígbà gbogbo kí á má ràrìn fẹsẹ̀ sí.

Ìròyìn sọ pé òpó iná mọ̀nàmọ́ná ti wó pa ọlọ́kadà kan àti obìnrin kan lágbègbè Iwo road ní ìlú Ìbàdàn.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, ọlọ́kadà náà àti obìnrin ọ̀hún ń dúnàdura lórí iye owó ni lásìkò tí òpó iná náà fi wó lùwọ́n tí iná ara wáyà orí rẹ̀ sì pa wọ́n.

Àwọn èèyàn agbègbè náà pe orúkọ ọlọ́kadà náà ní Kabiru ṣùgbọ́n wọ́n ní Olúyòlé ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ọ́ sí.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojú wọn ṣàlàyé pé olóúnjẹ ni arábìnrin náà, ó sì wá sí agbègbè náà ni láti wá gba ẹgbẹ̀rún kan náírà tí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́kọ̀ èrò lágbègbè náà jẹ ẹ́, kí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú náà tó ṣẹlẹ̀.

Ní báyìí,Iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, IBEDC ẹkùn Ìbàdàn, ti dárúkọ àwọn tí iná gbé náà tí wọ́n sì pé orúkọ wọn ní Ọ̀gbẹ́ni Ọladeji Ọlatunji pẹ̀lú Arábìnrin Kẹmi Degoke.

Wọ́n láwọn bá àwọn mọlẹ́bí wọn kẹ́dùn.

Nínú àtẹjáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Abámẹ́ta, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná lékùn Ìbàdàn, IBEDC, Ọ̀gbẹ́ni Jọhn Ayọdele ní àwọn ti ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí náà jíròrò lọ́nà àti tù wọ́n nínú bí ó ti wulẹ̀ ó mọ.

Bákan náà ló fi kún un pé ìgbésẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ lórí wíwádìí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹ̀ àti ohun gan tó ṣokùnfà rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Èèyàn méje kú n’Íbèṣè, nígbà táwọn ọlókadà kọjú ìjà síra wọn.

Èèyàn méje kú n’Íbèṣè, nígbà táwọn ọlókadà kọjú ìjà síra wọn. Ọrẹ Òtítọ́jù Ṣé wọ́n ní ìjàn…