Home ÀKỌ̀TUN Àwọn Tíṣà tó fi ṣọ́ọ̀kì kọ ìdánwò sójú pátákó fẹ́ bàmí lórúkọ jẹ́ ni– Ṣèyí Mákindé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 27, 2020

Àwọn Tíṣà tó fi ṣọ́ọ̀kì kọ ìdánwò sójú pátákó fẹ́ bàmí lórúkọ jẹ́ ni– Ṣèyí Mákindé

Àwọn Tíṣà tó fi ṣọ́ọ̀kì kọ ìdánwò sójú pátákó fẹ́ bàmí lórúkọ jẹ́ ni– Ṣèyí Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé èèyàn tí kò bá gbọ́ tẹnu ẹ̀gà, ni yóó pèé l’ẹ́yẹ aláròyé.
Bẹ́ẹ̀ a gbẹ́jọ́ ẹnìkan dá ni Yorùbá pè ní àgbà òsìkà.
Ọ̀rọ̀ kan tó ń jà rànìnrànìn láìpẹ́ yìí láàrin ẹgbẹ́ olùkọ́ àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,pé sọ́ọ̀ki làwọn olùkọ́ni káàkiri àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ́ọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ náà fi kọ ìbéèrè ìdánwò wọn sójú pátákó nítorí àìrí owó àkóso Ilé ẹ̀kọ́ gbà lọ́wọ́ ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé ló mú kí ìròyìn òwúrọ̀ fimúfínlẹ̀ wòye àrígbámú ọ̀rọ̀ náà.

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́, NUT ní ìpínlẹ̀ náà ti lọ s’órí atẹ́gùn láti pariwo síta pé ojú pátákó làwọn olùkọ́ kọ ìbéèrè ìdánwò sí fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ dípò títẹ ìbéèrè náà sínú ìwé nítorí ohun tí wọ́n pè ní kíkùnà ìjọba ìpínlẹ̀ náà láti san owó àkóso Ilé ẹ̀kọ́ ìwé, (school running grants) fún sáà ètò ẹ̀kọ́ méjì báyìí.

Àmọ́ṣá gómìnà Mákindé ti ṣàlàyé pé, àwọn ẹgbẹ́ olùkọ́ náà kò fẹ́ tú àṣírí ara wọn síta gbangba ni àti pé ó yẹ kí wọ́n jíjìn lórí owó tí wọ́n gbà ṣaájú fún àkóso àwọn Ilé ẹ̀kọ́.

Gómìnà Mákindé ní gbogbo owó tí Ìjọba fún wọn ṣaájú fún àkóso Ilé ẹ̀kọ́ ni òun ní kí wọ́n wá ṣe ìṣirò rẹ̀ kí wọ́n tó leè tẹ́wọ́ gba òmíràn.

Ó ní gbogbo àwọn tí wọ́n sọ ara wọ́n di eku ajẹnifẹ́ni tó ń jẹ owó ìlú yóó fojú ba àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìjẹkújẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYACA láìpẹ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…