Home ÀKỌ̀TUN Àrànkálẹ̀ Kófíìdì-19 lẹ́ẹ̀kejì,Akeredolu, Oyetola wọ́gilé ayẹyẹ Àìsùn ọdún ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọ̀ṣun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 24, 2020

Àrànkálẹ̀ Kófíìdì-19 lẹ́ẹ̀kejì,Akeredolu, Oyetola wọ́gilé ayẹyẹ Àìsùn ọdún ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọ̀ṣun

Àrànkálẹ̀ Kófíìdì-19 lẹ́ẹ̀kejì,Akeredolu, Oyetola wọ́gilé ayẹyẹ Àìsùn ọdún ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọ̀ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tí kò bá sèèyàn rí, a kìí sọ pé ó tún dé. Bẹ́ẹ̀ kójú ó má rí ibi, ẹsẹ̀ lòògùn un rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ara ọ̀nà láti dẹ́kun àrànkálẹ̀ ọwọ́ kejì àjàkálẹ̀ àrùn Kófíìdì-19, àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó àti Ọ̀ṣun ti fagilé gbogbo ìpéjọpọ̀ tó leè fẹ́ wáyé lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún yìí.

Ní tirẹ̀, Gómìnà Rótìmí Akérédolú ti ìpínlẹ̀ Òǹdó fagilé gbogbo ìpéjọpọ̀ wẹ̀jẹwẹ̀mu ọlọ́dọdún èyí tí Gómìnà Akérédolú fúnrarẹ̀ máa ń ṣagbátẹrù rẹ̀ ní ọjọọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá.

Amúgbálẹ́gbẹ̀ Gomina Akérédolú, Tosin Ogunbọdede sàlàyé nínú àtẹjáde kan pé ìgbésẹ̀ náà wáyé láti fi sèrántí àwọn èèkàn ọmọ ìpínlẹ̀ náà tó jáde láyé láìpẹ́ yìí àti láti tẹ̀lé àwọn Ìlànà ìgbógun ti àrùn Kófíìdì-19 tí ó tún búrẹ́kẹ́ síi l’ágbàáyé báyìí.

Gómìnà Akérédolú kò ṣàì rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà láti yọ ayọ̀ ọdún ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Bákan náà Gómìnà Gbóyèga Oyètọ́lá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti wọ́gilé gbogbo ayẹyẹ ọ̀dọ́ ládùgbóò sí àdúgbò tí a mọ̀ sí Youth Carnival káàkiri ìpínlẹ̀ náà.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní ayẹyẹ kíkí wákàtí wọnú ọdún tuntun tí a mọ̀ sí New year countdown tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà máa ń ṣe ní àṣálẹ́ àìsùn ọdún wọnú ọdún tuntun àtàwọn ìpéjọpọ̀ ńlá ńlá kò ni leè wáyé.

Akọ̀wé Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Wọlé Oyebamiji ṣàlàyé pé Ìlànà tuntun ti wà ńlẹ̀ báyìí fún àwọn egbẹ́jẹgbẹ́ àti aráàlú láti tẹ̀lé lọ́nà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn náà.

Lára àwọn Ìlànà tuntun náà ni pé ìwọnba èèyàn péréte ni ó gbọdọ̀ máa wà ní gbogbo àwọn Ilé ijó, ilé ìtura àwọn Ilé ìgbafẹ́ àti ilé ìtajà ńlá ńlá ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Oyètọ́lá wá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun láti dín pọ̀pọ̀sìnsìn ayẹyẹ, ìkómọ, ìsìnkú àtàwọn ayẹyẹ míràn kù kí wọ́n má baà lùgbàdi àkóràn àrùn náà.

Bákan náà ló ní àwọn iléèjọsìn gbọdọ̀ padà s’órí Ìlànà ìpéjọpọ̀ tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí dídènà àjàkálẹ̀ arun Kófíìdì-19.

Ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé lẹ́yìn tí ibùdó ìwádìí àrùn ACEGID ní Fásitì Redeemers RUN tó wà nílùú Ẹdẹ ti fìròyìn síta láìpẹ́ yìí pé àfàìmọ̀ kí ẹ̀yà tuntun kòkòrò àrùn Kófíìdì-19 tó ń ṣọṣẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan l’ágbàáyé ó má tíì wọ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…