Home ÀKỌ̀TUN Kófíìdì-19, ọsẹ̀ márùn ún gbáko l’òṣìṣẹ́ yóó tún fi sélẹ̀kùn mọ́rí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 22, 2020

Kófíìdì-19, ọsẹ̀ márùn ún gbáko l’òṣìṣẹ́ yóó tún fi sélẹ̀kùn mọ́rí

Kófíìdì-19, ọsẹ̀ márùn ún gbáko l’òṣìṣẹ́ yóó tún fi sélẹ̀kùn mọ́rí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ bá ń p ẹ́ nílẹ̀ ń ṣe ló máa ń gbọ́n mọ́ ọlọ́rọ̀ lọ́wọ́.
Bẹ́ẹ̀ n tó bá ṣe ọlọ́gbọ́n lẹ́ẹ̀kan, kò yẹ kó tún ṣe é lẹ́ẹ̀kejì.
Ní báyìí Ìjọba Nàìjíríà ti kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́ṣẹ̀ márùn ún gbáko fáwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀ lọ́nà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Kófíìdì-19.

Yàtọ sí àwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba tó wà ní ìpele Kejìlá lọ sí òkè, kò ní sí àwọn òṣìṣẹ́ míì tí yóó wá sí ibiṣẹ́ lásìkò yí.

Bákan náà ni ìkéde yìí sọ pé kí àwọn Ilé ẹ̀kọ́ gbogbo tí wọ́n yóó ti gba ìsinmi láti ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá wà ní títì pa fún ọ̀sẹ̀ márùn ún láti àsìkò yí lọ.

Lábẹ́ Ìkéde Ìlànà tuntun yí tí Alága Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó kíkọjú àrùn Kófíìdì-19 ní Nàìjíríà Boss Mustapha sọ, gbogbo Ilé oúnjẹ, ilé ìgbafẹ́ ni wọ́n ní kó wà ní títì pa.

Ó ní Ìgbìmọ̀ PTF ti ṣe àgbéyẹ̀wò gbogbo nǹkan tó ń lọ l’ágbàáyé, tí àwọn sì ti fi àbá tó yẹ ṣọwọ́ sí Ààrẹ Orílẹ̀ yìí fún bíbuwọ́lu ní kánmọ́ńkíá.

Àwọn nǹkan mìíràn tí Ìlànà tuntun yí mú ìyípadà bá ni:

Dídín iye èèyàn tí yóó wà níbi ayẹyẹ èyíkéyìí tàbí àpéjọpọ̀ sí pé kó má ju èèyàn àádọ́ta lọ.
Àwọn ilé oúnjẹ gbogbo ni yóó wà ní títì pa àyàfi àwọn tó bá ń ta oúnjẹ fún ilé ìtura tàbí tí àwọn èèyàn yóó ra oúnjẹ láti lọ jẹ nílé.
Àwọn èrò tí yóó kópa nínú ìjọsìn ilé ìsìn kò ní ju ìdáméjì iye èèyàn tó yẹ kí ó wà níbẹ̀ lọ
Àwọn ọlọ́kọ̀ èrò kò gbọdọ̀ kó ju ìdá méjì dédéé iye èèyàn tó yẹ kí wọ́n kó lọ
Kí àwọn èèyàn yàgò fún gbogbo ìrìnàjò èyí tí kò bá ti pọn dandan lásìkò yí

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…