Home ÀKỌ̀TUN Àwọn nǹkan tó le ṣekú pa ọkùnrin lásìkò ìbálòpọ̀ rèé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 18, 2020

Àwọn nǹkan tó le ṣekú pa ọkùnrin lásìkò ìbálòpọ̀ rèé

Àwọn nǹkan tó le ṣekú pa ọkùnrin lásìkò ìbálòpọ̀ rèé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ohun tí èèyàn kò bá mọ̀, yorùbá ní ó sàgbà èèyàn.

Lọ́pọ̀ọlọ̀ ìgbà la máa ń gbọ́ ìròyìn pé ọkùnrin tàbí obìnrin ré ṣọdá di èrò ọ̀run lásìkò ìbálòpọ̀.

Lára ohun tó ń fa irú ikú yí la gbọ́ pé àìlera wa, àì lè mí dáadáa tàbí àwọn ìpèníjà ara míràn.

Ṣùgbọ́n ìwádìí àwọn onímọ ti ń wáyé láti mọ ohun pàtó tó lè ṣokùnfà kí èèyàn kú lásìkò ìbálòpọ̀.

Ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọsẹ́ ìṣègùn òyìnbó nílẹ̀ yìí àti lókèèrè fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn a máa ṣokùnfà ikú àwọn èèyàn lásìkò ìgbádùn ìbálòpọ̀.

Wọ́n sàpèjúwe ìbálòpọ̀, bíi eré ìdárayá tí yóó mú kí ara èèyàn jí pépé . Fáwọn tí kìí bá ṣe ìgbaradì tàbí eré ìdárayá lóòrèkóòrè èyí lè mú kí wọ́n má kájú òsùnwọ̀n tó.

Lílo òògùn ṣaájú ìbálòpọ̀. Àwọn òògùn amárajípépé kan wà táwọn èèyàn máa ń rà láti lò fún ìbálòpọ̀ . Nínú wọn ni (Viagra) fíágírà wà.

T’ọ̀hún ti pé àwọn dókítà sọ pé ó lè mú kí nǹkan ọmọ ọkùnrin gbéra dáadáa, kò yẹ kí èèyàn máa lò ó ní gbogbo ìgbà tó bá fẹ́ ní ìbálòpọ̀

Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkùnrin tó bá ní àìsàn ọkàn (púpọ̀ ni kìí mọ̀ pé àwọn ní gan -an) máa ní ìpèníjà lásìkò ìbálòpọ̀ tí èyí á sì máa fa ikú fáwọn míràn tí ọkàn wọn kò bá gbé agbára òògùn náà.

Ohun táwọn dókítà sọ ni pé kí èèyàn lo ẹyọ kan tábúlẹ́ẹ̀tì òògùn yí ṣaájú ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n àwọn míì máa ń lò jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nítorí ìbálòpọ̀ a máa mú kí èèyàn ṣiṣẹ́ agbára, èyí lè ṣàkóbá fẹ́ni bá ní àìsàn ọkàn.

Èyí máa ń wáyé nígbà tí kaṣan tó ń gbé ẹjẹ kò bá lágbára tó, tí ẹ̀jẹ̀ bá ń gba inú rẹ̀ lásìkò ìbálòpọ̀, ó lè dìpọ̀ tí èyí yóó sì ṣàkóbá fẹ́ni náà.

Ọ̀nà mìíràn ni nígbà míì, pé, bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń tú gba inú kaṣan lásìkò ìbálòpọ̀ tí wọ́n ń pè ní ”adrenaline rush” lè mú ìnira wá lásìkò ìbálòpọ̀.

Kókó ọ̀rọ̀ ni pé bí ẹ̀jẹ̀ bá ń tú yaya nínú ara púpọ̀, tí kò bá ṣí atẹ́gùn tó ń gba inú ẹ̀jẹ̀ náà bó ti ṣe yẹ, èèyàn ń kọ lẹ́tà sí Ikú nì yẹn.

Ìwádìí fihàn pé ti èèyàn bá ń ní ìbálòpọ̀ púpọ̀ paàpá ẹni tó bá ní ìfúnpá tó ga, ó lè ṣàkóbá fún un .

Àwọn onímọ sọ pé ó ṣòro kí èèyàn tó bá gba ọ̀nà yí rọ lápá ó kú ṣùgbọ́n, èèyàn lè rọ lápá nípá ìbálòpọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…