Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀gá sọ́jà mérìndínlọ́gbọ̀n kó Kófíìdì-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 14, 2020

Ọ̀gá sọ́jà mérìndínlọ́gbọ̀n kó Kófíìdì-19

Ọ̀gá sọ́jà mérìndínlọ́gbọ̀n kó Kófíìdì-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ẹni ìjà ò bá níí pera rẹ̀ lọ́kùnrin,
àwọn Ọ̀gágun àgbà mérìndínlọ́gbọ̀n nílé iṣẹ́ ọmoogun Orílẹ̀ yìí ló ti lùgbàdi àrùn Kófíìdì -19 báyìí.

Ìgbàgbọ́ wa ni pé àwọn Ọ̀gágun náà ní ìbáṣepọ̀ àti ìfarakínra pẹ̀lú Ọ̀gágun Maj. Gen. Olú Irefin tí Kófíìdì-19 ṣekúpa lọ́sẹ̀ tó lọ.

Gbogbo àwọn Ọ̀gágun náà ló kópa nínú àpérò ọlọ́dọdún àwọn ológun tó wáyé nílùú Àbújá tó fi mọ́ Ọ̀gágun Ìréfín náà to di olóògbé.

Ìròyìn kan tún sọ pé Ọ̀gágun Ìréfín sàbẹ̀wò sáwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ kan ṣaájú àpérò wọn.

Níbáyìí, gbogbo àwọn ológun tó kópa nínú àpérò náà àtàwọn ẹbí wọn ló ti wà ní ìyàsọ́tọ̀ báyìí fún ọjọ́ mẹ́rìnlà gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ àjọ NCDC.

Àwọn elétò ìlera ti fín gbọ̀ngàn àpérò náà lágbègbè Asokoro láti pa kòkòrò àrùn náà níbẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…