Home ÀKỌ̀TUN Àdéhùn wà láàrín Buhari àti Tinubu lórí ìdíje ipò Ààrẹ lọ́dún 2023—Adelé alága APC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 13, 2020

Àdéhùn wà láàrín Buhari àti Tinubu lórí ìdíje ipò Ààrẹ lọ́dún 2023—Adelé alága APC

Àdéhùn wà láàrín Buhari àti Tinubu lórí ìdíje ipò Ààrẹ lọ́dún 2023—Adelé alága APC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí a bá taá , tí tọ̀ làá tọ̀ọ́, bí a kò bá fẹ́ kí ó di ẹran onídin.

Èyí ló mú kí adelé Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípìńlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Tunde Balógun ó máa ṣe é lálàyé pé Ààrẹ Muhammadu Buhari, Aṣíwájú Bọla Tinubu àtàwọn èèkàn míì nínú ẹgbẹ́ jọ ṣe àdéhùn lọ́dún 2014 pé apá ìwọ̀ òòrùn Gúúsù ni olùdíje fún ipò Ààrẹ lọ́dún 2023 yóó ti wá.

Ọ̀gbẹ́ni Balógun sọ pé kò ní bójú mu tí ẹgbẹ́ APC bá kọ etí ikún sí àdéhùn yìí.

Àwọn kan ti ń sọ pé àwọn ògúnná gbòǹgbò ọmọ ẹgbẹ́ APC kan ti ń gbìmọ̀pọ̀ láti gba ipò adarí ẹgbẹ́ náà àti láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023.

Ẹ̀wẹ̀, Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, NEC lábẹ́ adarí Ààrẹ Buhari ṣe àfikún àkókò tí Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Mai Mala Buni ṣagbátẹrù pẹ̀lú oṣù mẹ́fà síi.

Bákan náà ni Ìgbìmọ̀ NEC buwọ́lù àgbékalẹ̀ Ìgbìmọ̀ aláṣẹ tó ti di tújúká tẹ́lẹ̀.

Àmọ́, ohun tí Alága APC ìpínlẹ̀ Èkó ń sọ ni pé kí àwọn àgbààgbà tó dá ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ má gbàgbé àdéhùn ọdún 2014.

”Mo mọ̀ pé ènìyàn iyì làwọn aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àdéhùn kan tí wọ́n ní ló mú kí Buhari ṣojú ẹgbẹ́ náà nínú ìbò Ààrẹ ọdún 2015 àti ọdún 2019,” Ọ̀gbẹ́ni Balogun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ó ní ṣíṣe nǹkan míì yàtọ̀ sí àdéhùn ọdún 2014 kò ní ṣenu ‘re fún ẹgbẹ́ APC.

”Ìgbìmọ̀ fìdí hẹẹ́ tí àjọ NEC ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ṣùgbọ́n ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ ni mí, ń kò ní fẹ́ tako ẹgbẹ́,” Balógun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ó ní àwọn kan ń jà fita fita nítorí ti ara wọn láti ríi pé wọ́n ba ẹgbẹ́ òṣèlú APC jẹ́.

Balógun sọ pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀ tí ẹgbẹ́ bá gbárùkù ti Tinubu nítorí ó jẹ́ ọ̀kan lára àgbà òṣèlú nílẹ̀ Áfírìkà.

Ẹ̀wẹ̀, Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó tẹlẹrí tó jẹ́ mínísítà àkànṣe iṣẹ́ àti ilégbè báyìí, Babatunde Fashola náà sọ láìpẹ́ yìí pé ó ṣe pàtàkì kí APC rántí àdéhùn ọdún 2014.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…