Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà ìpínlẹ Eko, Babjide Sanwo-Olu ti lùgbàdì àrùn Covid -19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 12, 2020

Gómìnà ìpínlẹ Eko, Babjide Sanwo-Olu ti lùgbàdì àrùn Covid -19

Gómìnà ìpínlẹ Eko, Babjide Sanwo-Olu ti lùgbàdì àrùn Covid -19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ògédé ẹni Ọlọ́run bá pamọ́ nìkan ló bọ lọ́wọ́ ewu gbogbo to ń hu ọmọ aráyé ní dúníyàn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babájídé Sanwó-Olú ti lùgbàdi àrùn Coronavirus.

Kọmíṣọ́nnà ọ̀rọ̀ tó ń lọ, Gbenga Omotosho ló kéde bẹ́ẹ̀ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà, Akin Abayomi sọ pé àwọn akọṣẹmọsẹ
dókítà láti Ilé ìwòsàn tó ń ṣètọ́jú àjàkálẹ̀ àrùn ní Yaba ti ń ṣètọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́.

Ó ní “Ọ̀gbẹ́ni Sanwó-Olú ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́, a sì gbàgbọ́ pé yóó mórí bọ́ lọ́wọ́ àrùn náà láìpẹ́ ọjọ́.
Ìròyìn Òwúrọ̀ gbàá ládùúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ àlàáfíà pípé jẹ́ ìpín Gómìnà Babájídé Sanwó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…