Home ÀKỌ̀TUN Abdulrasheed Maina tún dákú nílé ẹjọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 11, 2020

Abdulrasheed Maina tún dákú nílé ẹjọ́

Abdulrasheed Maina tún dákú nílé ẹjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó dá bí ẹni pé ìdákú dájí kòì tán lọ́rọ̀ Maina o , bí ìròyìn ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Alága tẹlẹrí fún àjọ tó ń se àkóso owó ìfèyìntì, Abdulrasheed Maina ti dákú nílé ẹjọ́.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ọsẹ tó kọjá ni wọ́n di Maina ní àpáǹyáká wá sílé láti Orílẹ̀-èdè Niger tó sálọ, kó má baà fi ojú winá ìgbẹ́jọ́.

Àmọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ ní àárọ̀ àná Maina dákú, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti jí i padà sílé ayé.

Fídíò kan tó gba orí ayélujára kan, tó se àlàyé bí wọ́n se ń jí Maina nílé ẹjọ́ ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀.

A gbọ́ pé déédé aago mẹ́wàá kọjá Ìṣẹ́jú márùn ún ni Alága tẹlẹrí fún àjọ tó ń ṣàkóso owó ìfèyìntì dákú lásìkò ti agbẹjọ́rò rẹ̀, Anayo Adibe ń sọ̀rọ̀ níwájú adájọ́ Okon Abang.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì ló mú kí Ilé ẹjọ́ so ìjókòó rẹ̀ rọ̀ fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n láàyè láti ṣètọ́jú rẹ̀.
Ó sì pẹ́ díẹ̀, kí Maina tó yajú sáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…