Home ÀKỌ̀TUN Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC tú ilé ká nípele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 9, 2020

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC tú ilé ká nípele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ́

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC tú ilé ká nípele ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tú ilé ká! Kò sí àwọn aláṣẹ mọ́ ní ẹkùn, ìpínlẹ̀ àti làpapọ̀

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní Nàìjíríà ti tú gbogbo àwọn adarí ẹgbẹ́ ká ní ìpele ìpínlẹ̀, ẹlẹ́kùnjẹkùn àti Ìjọba àpapọ̀ wọn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejìlá ọdún 2020.

Èyí wáyé níbi ìpàdé Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ náà tó wáyé lórí ayélujára nípaṣẹ̀ Zoom ní ilé Ààrẹ, Aso Rock nílùú Àbújá.

Lára ohun tó tún ṣẹlẹ̀ ni pé Ìgbìmọ̀ aláṣẹ jáwé lọ̀ọ́ gbélé ẹ fún ìgbákejì alága ẹgbẹ́ tẹlẹrí ní ẹkùn Gúúsù- Gúúsù, Hilliard Eta.
Gómìnà Kàdúná, Nasiru El-Rufai ṣàlàyé lẹ́yìn ìpàdé náà pé ìdí tí wọ́n fi fọwọ́ òsì júwe ilé fún Eta ni pé ó kùnà láti jámi lọ́rọ̀ ẹjọ́ kan tó lòdì sí Ìgbìmọ̀ fìdíhẹẹ́ ẹgbẹ́.

Ẹ ó rántí pé ẹgbẹ́ náà ti ṣètò látinú oṣù Kọkànlá, láti ṣèpàdé tí wọn yóó fi ṣàgbéyẹ̀wò ipò ti wọ́n wà àti ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ tuntun látàrí ètò ìdarí ẹgbẹ́ náà.
Alága Ìgbìmọ̀ fìdíhẹẹ́ àti Ìgbìmọ̀ alákànṣe ètò tó fi mọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe, Mai Mala Buni ló darí àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ tó kù pẹ̀lú Ààrẹ Buhari nínú ìpàdé náà.

Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Sẹ́nétọ̀ Ahmad Lawan àti adarí Ilé Ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin, Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà wà níbi ìpàdé náà lójúkorojú.

Bákan náà, àwọn gómìnà APC èyí tí alága ẹgbẹ́ àwọn gómìnà, Káyọ̀dé Fáyemí àti gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe, Atiku Bagudu náà wà níbẹ̀ lójúkorojú .

Níbáyìí, ìgbìmọ̀ aláṣẹ tún ti fikún sáà tí Ìgbìmọ̀ fìdíhẹẹ́ alákànṣe ètò ẹgbẹ́ náà, èyí tí Gómìnà Mai Buni ń dari. Wọ́n fi oṣù mẹ́fà kún sáà tí wọn yóó lò.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…