Home ÀKỌ̀TUN Àwọn tó ṣàkóso iṣẹ́ àgbàṣe Iléẹ̀kọ́ Ọba Akinbiyi lẹ́jọ́ ọ́ jẹ́–Ṣèyí Mákindé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 18, 2020

Àwọn tó ṣàkóso iṣẹ́ àgbàṣe Iléẹ̀kọ́ Ọba Akinbiyi lẹ́jọ́ ọ́ jẹ́–Ṣèyí Mákindé

Àwọn tó ṣàkóso iṣẹ́ àgbàṣe Iléẹ̀kọ́ Ọba Akinbiyi lẹ́jọ́ ọ́ jẹ́–Ṣèyí Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní èèyàn tó bá mọ nǹkan fi pamọ́ , kó rántí ẹni tó mọ̀ ọ́ wá. Bẹ́ẹ̀,iyán ogún ọdún a máa jó ni lọ́wọ́ fàìfàì.
Láìpẹ́ yìí ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàṣẹ ìwádìí lórí bí wọ́n ṣe fa ìwé iṣẹ́ àgbàṣe oní irinwó mílíọ̀nù náírà fún kíkọ́ Iléẹ̀kọ́ girama ìgbàlódé Ọba Akinbiyi tó wà lágbègbè Ọrẹmeji ní ìlú Ìbàdàn ya.

Ní ọjọ́ Ajé ni Gómìnà Mákindé pa àṣẹ yìí lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ náà níbi tí ìròyìn sọ pé ó ti rí àwọn àríwísí tí kò ṣe é fojú fò dá.

Gómìnà Mákindé ṣàlàyé pé láì tí ì ju ọdún kan lọ, ògiri, àtàwọn ohun ẹ̀ṣọ́ ìwọ́lẹ̀ táìlì tí wọ́n lò ti ń bàjẹ́ pẹ̀lú àfikún pé kò dájú pé wọ́n kọ́ Ilé náà bí ó ti ṣe yẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tó tọ̀nà fún kíkọ́ ilé.

Ó ní orúkọ iléèwé náà gan ti wọ́n kọ s’órí pátákó ti ń ṣí dànù.

O ní àwọn èèyàn tó wà nídìí ìkọ́lé náà nígbà náà yóó dáhùn ìbéèrè lórí ìdí tí wọ́n fi kọ́kọ́ fa ìwé iṣẹ́ náà ya lọ́wọ́ kọngílá tí wọ́n gbé e fún, bákan náà ló ní wọn yóó tún dáhùn ìbéèrè lórí bí wọ́n ṣe gbé iṣẹ́ náà fún ètò ojú àwò làwo fi í gbọbẹ̀, ‘direct labour’ pẹ̀lú irinwó mílíọ̀nù náírà tí ó sì tún jẹ́ pé iṣẹ́kíṣẹ́ ni wọ́n ṣe.

Àmọ́ ṣá ọ̀kan lára àwọn Kọmíṣọ́nnà ní ìṣèjọba Gómìnà Ajímọ̀bi nígbà náà, Ọjọ́gbọn Olowofẹla ti ké sí Mákindé pé kó fi olóògbé Ajímọ̀bi lọ́rùn sílẹ̀ .

Olowofẹla tó jẹ́ Kọmísọ́nnà fétò ẹ̀kọ́ nígbà náà ṣàlàyé pé ìgbà tí iṣẹ́ náà ń fa lẹ̀ lọ́wọ́ agbaṣẹ́ṣe tí wọ́n gbé e fún tó sì hàn gbangba pé agbaṣẹ́ṣe náà kò lágbára iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un náà ni Gómìnà pàṣẹ kí wọ́n gba iṣẹ́ àgbàṣe náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ kí wọ́n gbé e fún iléeṣẹ́ Ìjọba tó ń mójútó iṣẹ́ òde láti parí.

Ó ní ó yẹ kí Mákindé ó yẹ gbogbo ìwé àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ náà wò kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀ àlùfàǹṣá sí olóògbé Ajímọ̀bi tó jẹ́ Gómìnà nígbà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ àkànṣe náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…