Home ÀKỌ̀TUN Ìyanṣẹ́lódì ASUU, Ìjọba àpapọ̀ ni ẹ bẹ̀– Ẹgbẹ́ ASUU
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 17, 2020

Ìyanṣẹ́lódì ASUU, Ìjọba àpapọ̀ ni ẹ bẹ̀– Ẹgbẹ́ ASUU

Ìyanṣẹ́lódì ASUU, Ìjọba àpapọ̀ ni ẹ bẹ̀– Ẹgbẹ́ ASUU

Fẹ́mi Akínṣọlá

Alága Ẹgbẹ́ olùkọ́ni Fásitì ní Nàìjíríà, ASUU, nípìńlẹ̀ Èkó , Ọ̀mọ̀wé Dele Ashiru sọ pé òun kò gbọ́ nípa ìpàdé tí ìjọba àpapọ̀ sọ pé òun yóó ṣe ní ọ̀sẹ̀ yìí pẹ̀lú àwọn olùkọ́.

Ọ̀mọ̀wé Ashiru sọ pé ìyanṣẹ́lódì sì ń lọ lọ́wọ́, nítorí pé àwọn kò tíì yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀.

Ó sọ èyí gẹ́gẹ́ bí èsì sí ìkéde tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fi síta pé òun yóó ṣèpàdé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ASUU ní ọ̀sẹ̀ yìí láti yanjú nǹkan tó mú kí ẹgbẹ́ náà wà ní ìyanṣẹ́lódì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ Ìròyìn Channels, Mínísítà fún ètò ìgbani ṣíṣẹ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́, Ọ̀mọ̀wé Chris Ngige fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjíròrò yóó bẹ̀rẹ̀ padà pẹ̀lú àwọn Olórí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àgbà ní Fásitì, SSANU àti àwọn aláṣẹ ètò ẹ̀kọ́ láti yanjú ọ̀rọ̀ tó wà láàrin ìjọba àti ẹgbẹ́ ASUU.

Ọ̀mọ̀wé Ngige ní òun ní ìrètí pé wọn ó rí ọ̀rọ̀ náà yanjú ní ọ̀sẹ̀ yìí , tí ètò ẹ̀kọ́ yóó sì bẹ̀rẹ̀ padà ní àwọn Fásitì.
Bákan náà ló sọ pé Ìjọba àpapọ̀ ń ṣe àwọn ìpàdé míràn lábẹ́nú, níbi tí wọ́n ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan pàtàkì tí yóó yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Ìlànà ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tí Ìjọba fẹ́ ẹ́ má a fi san owó oṣù àwọn olùkọ́ náà (Integrated Payroll and Personal Information System, IPPIS) ló fa ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé.

Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU, Biodun Ogunyemi sọ pé ìnira ni ìlànà tuntun náà yóó mú bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé iléeṣẹ́ tó ń mójútó ìmọ̀ ẹ̀rọ IPPIS má ń yọ lára owó oṣù àwọn.

Ó ní Ìlànà tí àwọn Fásitì ṣe fúnra wọn, ìyẹn ‘University Transparency and Accountability Solutions’, ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ fẹ́ ẹ́ fi má a gba owó oṣù wọn.

“Tí ìjọba bá ti faramọ́ nǹkan tí a fẹ́, àwa náà setán láti padà sí ẹnu iṣẹ́ wa.”

Oṣù Kẹta, ọdún 2020, ni ẹgbẹ́ ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì aláìnígbèdéke.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…