Home ÀKỌ̀TUN Ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n ṣemí lófò ìyàwó àt’ọmọ mẹ́ta–Shina Rambo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 9, 2020

Ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n ṣemí lófò ìyàwó àt’ọmọ mẹ́ta–Shina Rambo

Ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n ṣemí lófò ìyàwó àt’ọmọ mẹ́ta–Shina Rambo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sí ẹni tí Ọlọ́run kò lè fí ọwọ́ tọ lẹ́mìí pẹ̀lú ayípadà ọkàn.
Gbajúgbajà ògbójú adigunjalè n-nì àmọ́ tó ti wá di òjíṣẹ́ Ọlọ́run báyìí, Shina Rambo tún ti yọjú sígboro.

Ranbo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pariwo pé ó ti kú, ló ní alààyè ni òun, iṣẹ́ Olúwa sì ni òun ń se.

Shina Rambo, tó jẹ́ gbájúmọ́ ọ̀daràn táyé ń polongo rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí, kí ọwọ́ òfin tó tẹ̀, ló tún yọjú kulẹ sílùú Adó Èkìtì, láti kópa lórí ètò rédíò kan.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde kan tíléesẹ́ akọròyìn ilẹ̀ wa, NAN fisíta, alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni Rambo kópa lórí ètò rédíò Fresh FM, tí gbajúgbajà akọrin Tùǹgbá n-nì, Yinka Ayefele fúnra rẹ̀ darí.
Rambo, ẹni tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Olúwásínà Olúwagbémiga ló sàlàyé pé òun ti di òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti ajíyìnrere fún Jésù, tí ìyípadà ńlá sì ti bá ayé òun.

Ó wá jẹ́wọ́ pé òun gan ni ògbóǹtarìgì ọlọ́ṣà tó ń mì ìlú tìtì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, bí òun sì se ń jalè, ni òun tún ń pa aláìṣẹ̀, tí òun sì ń fi imú agbófinró dánrin.

Rambo ní ọ̀pọ̀ agbófinró ni ẹnu yóó yà láti gbọ́ pé òun tí wọ́n ní òun ti kú ló sì wà láàyè lónìí.

“Bàbá mi jẹ́ gbájúmọ́ ẹ̀dá àti ológun tó ń lọ láti agbègbè kan sí òmíràn yíká orílẹ̀-èdè yìí.

Lọ́nà àti gba agbára òkuǹkùn, ibi mọ́kànlélógún ni mo lọ, lára wọn ni Minna nípìńlẹ̀ Niger àti òró nípìńlẹ̀ Kwara.”

“Mo wà nílù ìdànrè nípìńlẹ̀ Òǹdó fun ọdún mọ́kànléláàdọ́rùn, níbi tí wọ́n ti ní kí n máa mu ọmú obìnrin kan gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ àti omi, kí agbára òkuǹkùn le wọnú ara mi.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, mo ní agbára òkuǹkùn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá àti ẹyọ kan, 901, èyí tí mò ń lò láti máa pòórá lásìkò tí mo bá hùwà ọ̀daràn, tàbí sọ ara mi di ẹlòmíràn.

Tí wọ́n bá pa mí níbìkan, mo ní agbára láti jí dìde, kí n sì tún fara hàn ní ibòmíràn.”

Àmọ́ Ìròyìn náà ní Rambo wá kábàámọ̀, tó sì ń fi ìka hánu lórí àwọn ìwà àìdáa tó hù náà èyí tó fi dá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jókòó fún ọpọ ọdún, tó sì ní àwọn ẹ̀mí àìm ló fàá.

Rambo ní ní kété tí òun fi ayé òun fún Jesu ní ẹ̀mí Ọlọ́run wọ inú òun lọ, tó sì pàṣẹ fún òun láti jọ̀wọ́ gbogbo agbára òkuǹkùn náà àti ìwà burúkú, kí òun sì máa wàásù .

Ó ní òun ti jèrè ọkan púpọ̀ fún Ọlọ́run láti ipaṣẹ̀ ìwàásù tí òun ń se, tí òun sì tún ti dá ọ̀pọ̀ ilé ìjọsìn sílẹ̀ pẹ̀lú.

Ògbóǹtarìgì adigunjalè tẹ́lẹ̀rí náà ní ohun tí òun kábàámọ̀ jùlọ ni Ikú aya òun àti ọmọ mẹ́ta, tí àwọn tó wá mú òun, àmọ́ tí wọn kò bá òun pa.

Shina Rambo wá pàrọwà sáwọn èèyàn tó sì ń hùwà ọ̀daràn láti jáwọ́, kí wọ́n sì ronúpìwàdà, kí ìbínú Ọlọ́run má baà dé bá wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…