Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún CBN kó so ẹnu àpò àsùnwọ̀n ogún èèyàn tó ṣagbátẹrù ìwọ́de
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 7, 2020

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún CBN kó so ẹnu àpò àsùnwọ̀n ogún èèyàn tó ṣagbátẹrù ìwọ́de

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún CBN kó so ẹnu àpò àsùnwọ̀n ogún èèyàn tó ṣagbátẹrù ìwọ́de

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga Ìjọba àpapọ̀ nílùú Àbújá ti fi àṣẹ sí i pé kí Báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, gbẹ́sẹ̀lé àpò àsùnwọ̀n èèyàn ogún tó ṣagbátẹrù ìwọ́de #ENDSARS títí di oṣù Kínní, ọdún 2021.

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìdájọ́ náà ṣe fihàn, Onídàájọ́ Ahmed Mohammed ló fún CBN ní àṣẹ náà, ogúnjọ́ oṣù Kẹwàá, sì ni Báńkì àpapọ̀ ọ̀hún gbé ìwé ẹ̀bẹ̀ lọ sílé ẹjọ́.

Oṣù tó kọjá ni ìwọ́de #ENDSARS wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà, àti nílẹ̀ òkèèrè, èyí tó mi ilẹ̀ jákèjádò.

Ìwọ́de náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ní Nàìjíríà fi polongo fún fífi òpin dé bá ẹ̀ka iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń gbógun ti ìwà ìdigunjalè, Special Anti-Robbery Squad, SARS.

Àwọn ẹ̀sùn ìfìyàjẹni, ìpànìyàn, àti ìwà ìlọ́nilọ́wọ́gbà ni wọ́n fi kan àwọn ọlọ́pàá SARS.
Ìwọ́de náà ti kọ́kọ́ ń lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀, kó tó di ranto bí àwọn ọmọ ìṣọ̀ta ṣé já a gbà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ tó ti ń wáyé.
Èyí tó bí ìfẹ̀mísòfò tí kò ṣe é díyelé bá àwùjọ Orílẹ̀ yìí.

Kódà, wọ́n dáná sun àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, ilé ìtajà, àti ọkọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ bí i Ọ̀yọ́, Èkó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn kan lára wọn sì tún kó àwọn oníṣòwò ní ẹrù lọ lẹ́yìn tí Ìjọba kéde kónílé-ó-gbélé.

Àwọn tí Báńkì àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé àpò àsùnwọ̀n wọn nìyí:

•Bolatito Rachael Oduala

•Chima David Ibebunjoh

•Mary Doose Kpengwa

•Gatefield Nigeria Limited

•Saadat Temitope Bibi

•Bassey Victor Israel

•Wisdom Busaosowo Obi

•Nicholas Ikhalea Osazele

•Ebere Idibie

•Akintomide Lanre Yusuf

•Uhuo Ezenwanyi Promise

•Mosopefoluwa Odeseye

•Adegoke Pamilerin Emmanuel

•Umoh Grace Ekanem

•Babatunde Victor Segun

•Mulu Louis Teghenan

•Mary Oshifowora

•Winifred Akpevweoghene Jacob

•Victor Solomon

•Idunu A. Williams

Àwọn Báńkì bí i Access, Fidelity, First Bank Nigeria, Guaranty Trust Bank, United Bank of Africa, àti Zenith, ni ilé ẹjọ́ fi ìwé àṣẹ ránṣẹ́ sí .

Ó sì tún sún ìgbẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà sí ọjọ́ kẹrin, oṣù Kejì, ọdún 2021.

Bákan náà ló sọ pé ẹnikẹ́ni tí àṣẹ náà bá báwí, le kọ̀wé sílé ẹjọ́ láti gbọ́ àwíjàre rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…