Home ÀKỌ̀TUN Ìdìbò Amẹrika, Esther Agbaje, Oye Owolewa àti Nnamdi Chukwuocha jáwé olúborí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 7, 2020

Ìdìbò Amẹrika, Esther Agbaje, Oye Owolewa àti Nnamdi Chukwuocha jáwé olúborí

Ìdìbò Amẹrika, Esther Agbaje, Oye Owolewa àti Nnamdi Chukwuocha jáwé olúborí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta, tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti jáwé olúborí nínú ìdìbò tó ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè ọ̀hún.

Àwọ́n ọmọ Nàìjíríà náà ni; Esther Agbaje, Oye Owolewa àti Nnamdi Chukwuocha.

Esther Agbaje ló díje láti ṣojú ẹkùn 59B ní Minnesota, ìyẹn nílé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ Democratic, tó sì ní ìbò 17,396.

Ẹni ọdún márùndínlógójì náà fi ẹ̀yìn Alan Shilepsky gbolẹ̀, èyìí tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican, àti Lisa-Delgado ti Green Party.
Agbaje tó kàwé gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin láti Fásitì Harvad jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn án tó ń kópa nínú ètò ìdìbò ọ̀hún.

Saájú àkókò yìí, Agbaje ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ Ìjọba ilẹ Amilẹ̀ka, US State Department, bẹ́ẹ̀ ló tún ṣiṣẹ́ niIléeṣẹ́ àwọn Amòfin kan lẹ́yìn tó kọ́kọ́ kẹ́kọ́ọ̀ gboyè ní Fásitì Pennsylvania.
Esther Agbaje ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí yó jẹ ọmọ ilé aṣojú-sòfin ní Minnesota.

Ọmọ Nàìjíríà míràn tó borí nínú ìdìbò ọdún 2020 ni Nnamdi Chukwuocha tí wọ́n dìbò yàn láti ṣojú ẹkùn kínní ti ìpínlẹ̀ Deleware nílé Ìgbìmọ̀ aṣojú.

Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Democrat tí kò ní alátakò kankan, Chukwuocha borí nínú ìdìbò ọ̀hún pẹ̀lú ìbò 7,640.
Saájú ni wọ́n ti kọ́kọ́ yan Chukwuocha láti ṣojú ẹkùn kínní ní ilé Ìgbìmọ̀ aṣojú Deleware lọ́dún 2018.

Chukwuocha kẹ́kọ́ọ̀ nípa ìtàn ní Fásitì ìpínlẹ̀ Deleware, ó sì ní ìrírí nípa ètò òṣèlú abẹ́lé ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ọmọ Nàìjíríà kẹta tí yóó di ipò òṣèlú mú l’Amẹ́ríkà báyìí ni Oye Owolewa.

Owolewa gbégbá orókè nínú ìdìbò náà lẹ́yìn tó fi ẹ̀yìn àwọn alátakò rẹ̀, Joyce Robinson-Paul àti Sohaer Syed gbolẹ̀.

Owolewa ní ìbò 164,026, nígbà tí Robinson-Paul ní ìbò 18,600, tí Syed sì ní 15,372.

Ọmọ Nàìjíríà ọ̀hún kẹ́kọ́ọ̀ gboyè Ọ̀mọ̀wé ní Northeastern University, ìyẹn ní ìlú Boston.

Òun ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ nínú ìwé ìtàn tí yóó di ipò yìí mú ní agbègbè Colombia.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…