Home ÀKỌ̀TUN Bàbá àádọ́ta ọdún ó lékan fipá bá ọmọ ọdún méjìlá lòpọ̀ l’Ékìtì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 4, 2020

Bàbá àádọ́ta ọdún ó lékan fipá bá ọmọ ọdún méjìlá lòpọ̀ l’Ékìtì

Bàbá àádọ́ta ọdún ó lékan fipá bá ọmọ ọdún méjìlá lòpọ̀ l’Ékìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikún ń jọ̀gẹ̀dẹ̀, ikún ń rẹ́dìí, ikún ò tètè mọ̀ pé ohun tó dùn ń pani.
Ara Ààtò tí wọ́n là kalẹ̀ láti fòpin sí ìwà ìfipábánilòpọ̀ láwùjọ, Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì ti lẹ orúkọ arákùnrin kan sí ojú táyé látàrí pé wọ́n gbáamú pé ó fipá bá èèyàn lòpọ̀.

Arákùnrin náà, Ajayi Peter ẹni ọdún ọ̀kànléláàdọ́ta tó jẹ́ ọmọ ìlú Itapa Èkìtì ti gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére ni ilé ẹjọ́ gíga ìlú Adó Èkìtì fún un pé ó fipá bá ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá lò pọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tó jáde láti ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ Èkìtì, bí wọ́n ṣe fí orúkọ àti dídójú ti ni ni gbangba wa ní ìtẹ̀síwájú ìpinnu Ìjọba láti má fààyè gba ìwà ìfipábánilòpọ̀ mọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà, àtẹjáde ọ̀hún fihàn pé lábẹ́ àkóso àfikún ìgbésẹ̀ ti agbẹjọ́rò àgbà náà tún gbé jáde, wọ́n yóó tún lẹ orúkọ àti àwòrán àwọn afipábánilò tí òfin bá gbámú sí àdírẹ́sì ilé tí wọ́n bá mọ̀ wọ́n mọ́ àti ní ibi tó bá gbajúmọ̀ dáadáa ládùgbóò ibi ti ẹni tó ṣe aṣemáṣe yìí ń gbé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…