Home ÀKỌ̀TUN Ìpànìyàn Lekki, a ní ẹ̀rí tó dájú–Amnesty lnternational
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 28, 2020

Ìpànìyàn Lekki, a ní ẹ̀rí tó dájú–Amnesty lnternational

Ìpànìyàn Lekki, a ní ẹ̀rí tó dájú–Amnesty lnternational

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà ló ní bí ogún bá jẹ́ lọ, ọgbọ́n ń jẹ bọ.
Àjọ ajàfẹ́tọ́ọ̀ ẹni kan l’ágbàáyé, Amnesty International, ti kìlọ̀ fún Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti má bo àṣírí bí àwọn kan ṣe yìnbọn mọ́ àwọn olùwọ́de ní Lekki, nípìńlẹ̀ Èkó.

Olùdarí Àjọ náà, Osai Ojigho sọ pé àwọn fi ìkìlọ̀ náà síta, nítorí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé báyìí fihàn pé ìjọba fẹ́ bo àṣírí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí iléeṣẹ́ ológun bá pààyàn lọ́nà tí kò bá òfin mu ní Nàìjíríà.

Iléeṣẹ́ ológun ti kọ́ sọ pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n tó tún yí ọ̀rọ̀ padà lọjọ Ìṣẹ́gun pé, Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ló ránṣẹ́ pe àwọn láti dá àlàáfíà padà sí ààrin ìlú.

Àmọ́ ‘sá, Gómìnà paàpá ti kọ́ sọ pé òun kò fún wọn ní àṣẹ nítorí pé òun kò ní agbára láti pàṣẹ fún iléeṣẹ́ ológun.

Àjọ Amnesty sọ pé òun ní ẹ̀rí tó pọ̀, láti fihàn pé àwọn ọmọ ogun ló yìnbọn mọ́ àwọn olùwọ́de náà, èyí tó pa àwọn kan, tí àwọn míì sì farapa.

Àti pé, àwọn onímọ nípa rògbòdìyàn nínú àjọ náà ti ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí i dájú pé iléeṣẹ́ ológun lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn tó wáyé ní Lekki.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…