Home ÀKỌ̀TUN Àgbàrá òjò gbé alága àdúgbò àti èèyàn méjì mìí lọ nílùú Ibadan
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 27, 2020

Àgbàrá òjò gbé alága àdúgbò àti èèyàn méjì mìí lọ nílùú Ibadan

Àgbàrá òjò gbé alága àdúgbò àti èèyàn méjì mìí lọ nílùú Ibadan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní omi kò lápá,omi kò lẹ́sẹ̀, omi ń wọ́ yanrìn gẹẹrẹ gẹ.

Àgbàrá òjò gbe Alága àdúgbò àti àwọn èèyàn méjì míì lọ nílùú Ìbàdàn.

Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní àdúgbò Oke-Odo tó ń bẹ ní agbègbè Igisogba Omo-Adio ìlú Ìbàdàn níbi tí àgbàrá òjò ti gbé Alága àdúgbò náà àti àwọn èèyàn méjì míì lọ lọ́jọ́ Ajé.

Àtẹjáde tí iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Double A Media fi léde ló fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé àrọ̀rọ̀dá òjò ló ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.

Méjì nínú àwọn olùgbé agbègbè náà tó bá àwọn oníròyìn ṣọ̀rọ̀, Arákùnrin Alimi Olumuyiwa àti Wasiu Adeshina ṣe àlàyé pé èèyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rì sínú àgbàrá òjò lọ́jọ́ Ajé.

Lára wọn ni Alága adugbo naa, Arakunrin Nureni Adejumo ti gbogbo eeyan mọ si “Master” wa.

Síwájú síi, ọmọ Alága náà Onímọ̀ ẹ̀rọ Nurudeen Adejumo sọ fún àwọn oníròyìn pé òun gba ìpè pàjáwìrì ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà wí pé àgbàrá òjò ti gbé bàbá òun lọ tí ó sì ti di àwa wati bayii.

Ó tẹ̀síwájú wí pé ohun ìbànújẹ́ ńlá gbáà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń mú un wá sí ìrántí wí pé àìbìkítà Ìjọba náà ló ṣekúpa ìyá ọun ní nǹkan bí i ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Níbáyìí gbogbo àwọn olùgbé agbègbè náà ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé láti dìde ìrànlọ́wọ́ lórí afárá kan tó nílò àtúnṣe ní agbègbè náà láti bí i ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ má baà wáyé mọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…