Home ÀKỌ̀TUN Àjọ NBC sán konko ìyà mọ́ AIT, Arise TV àti Channels
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 26, 2020

Àjọ NBC sán konko ìyà mọ́ AIT, Arise TV àti Channels

Àjọ NBC sán konko ìyà mọ́ AIT, Arise TV àti Channels

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé òfin gbogbo n tójú bá rí kọ lẹnu-ún sọ ti ìjọba ń laago ìkìlọ̀ rẹ̀ gbọnmọgbọnmọ ti ń rẹ́sẹ̀ walẹ̀ báyìí o, látàrí bí Àjọ tó ń mójútó ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ní Nàìjíríà, NBC, tí nawọ́ ẹgba ìbáwí rẹ̀ sí iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mẹ́ta, AIT, Arise TV, àti Channels.

Àjọ náà fi ẹ̀sùn kan wọ́n pé wọ́n tàpá sí òfin tó de ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, nípa ṣíṣe àfihàn àwọn fídíò tí wọn kò ṣe ìwádìí rẹ̀.

Adélé Ọ̀gá àgbà Àjọ NBC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Armstrong Adachaba, kéde èyí níbi ìpàdé oníròyìn kan tó wáyé nílù Abuja lọ́jọ́ Ajé.

Àjọ NBC sọ pé àwọn iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fi àwọn fídíò nípa ìbọn yínyìn tó wáyé ní Lekki síta, láì wádìí bóyá òtítọ́ ni wọ́n tàbí ayédèrú.

Gẹ́gẹ́ bí Ìkéde tí àjọ náà fi síta, owó ìtanràn tí wọn yóó san wà láàrin mílíọ̀nù méjì sí mílíọ̀nù mẹ́ta Náírà.

Ọ̀sẹ̀ tó lọ ni àjọ náà ti kọ́kọ́ fi àtẹjáde síta, láti fún àwọn iléeṣẹ́ agbúhùnsáfẹ́fẹ́ ní ìlànà tí wọn yóó tẹ̀lé lórí ìwọ́de náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…