Home ÀKỌ̀TUN Ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn tó ń wáyé káàkiri Nàìjíríà– Babangida
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 24, 2020

Ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn tó ń wáyé káàkiri Nàìjíríà– Babangida

Ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn tó ń wáyé káàkiri Nàìjíríà– Babangida

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olè kò níí jàgbà, kò má ṣe é lójú fìrí. Adarí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ Ìjọba ológun nígbà kan rí, Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ti ní kò sí rògbòdìyàn kankan tó le bẹ́ sílẹ̀ ju wákàtí mẹ́rìnlélógún lo tí kò sí ọwọ́ Ìjọba níbẹ̀.

Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ló fi léde bẹ́ẹ̀ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kojú rògbòdìyàn lásìkò ìfẹ̀hónúhàn tako ìfìyàjẹni àwọn ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Babangida ní òun sọ ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gágun Sani Abacha sọ nígbà ayé rẹ̀ pé ” tí rògbòdìyàn bá ti ju wákàtí mẹ́rìnlélógún lọ, òṣìṣẹ́ Ìjọba kan wà ní ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà nìyẹn.”

Ó fikún un wí pé adarí rere ló le è tukọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò tí á wà yìí, nítorí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ní ó máa ń fihàn bóyá ènìyàn jẹ́ adarí rere àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Bákan náà ni Babangida bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣekúpani àwọn afẹ̀hónúhàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí àwọn ikọ̀ Ológun Nàìjíríà da ìbọn bò wọ́n ní agbègbè Lekki Tollgate ní ìlú Èkó àti káàkiri Nàìjíríà pẹ̀lú.

Babangida ní kòsí ọmọ Nàìjíríà kankan tó yẹ kó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù lórí pé òun bèèrè fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ Ìjọba tiwantiwa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…